Nigeria Election 2019: Báwo ni ìdìbò ònì yóò ṣe lọ?

Oni lọjọ ti gbogo ọmọ Naijiria ti n reti bẹẹ si ni awọn orilẹede agbaye náà si n reti lati mọ iru ọmọ ti idibo yii yoo bi.

Ọjọ abamẹta ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji lo yẹ ki idibo naa kọkọ waye ṣugbọn fun awọn idi ti ajọ INEC ṣalaye, wọn sun ibo naa siwaju lowurọ ọjọ kẹrindinlogun si ọjọ kẹtalelogun oṣu keji ọdun 2019.

Awọn oju ti kii ṣaimọ f'oloko ni Naijiria ti yoo maa du ipo aarẹ da lori ifẹ onikaluku oludibo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images/@Sowore/@Atiku/@Moghalu/@Durotoye

Àkọlé àwòrán,

Awọn oludije to lewaju ninu idibo Aarẹ Naijiria

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti ṣe ipinu lati ṣi lọ dibo dipo isunsiwaju ti ajọ INEC ṣe.

Deede agogo mẹjọ owurọ ni eto idibo yoo bẹrẹ pẹlu ṣiṣe ayẹwo orukọ awọn oludibo kaakiri awọn ibudo idibo to wa.

Oríṣun àwòrán, YASUYOSHI CHIBA

Àkọlé àwòrán,

Awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo

Àkọlé fídíò,

Ẹ wo oun tí ìbejì yìí ṣe nítorí ìgbéyàwó wọn bọ́ sí ọjọ́ ìdìbò ààrẹ

Ko si ṣiṣe ko ṣaiṣe, gbogbo oju opo iroyin ni yoo kun fọfọ bi awọn eniyan lagbaye yoo ṣe maa reti ẹkunrẹrẹ iroyin.

Bi o ba wa ṣe ti iroyin to yanranti ti ko lẹja n bakan ninu, nipa idibo to n lọ, lede abinibi, itakun ayelujara bbc.com/yoruba, facebook bbcnewsyoruba, instagram @bbcnewsyoruba nikan lẹ́ ti lee ri iru ẹ nitori naa, ẹ maa pin awọn iroyin wa kaakiri ki gbogbo eniyan lee janfani rẹ.

Àkọlé fídíò,

#NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí