Nigeria 2019 Elections: Eko, Anambra àti Rivers ló ṣeéṣe kí àtúnbì ìbò ti wáyé

Apoti ibo ti wọn danu

Eto idibo aarẹ ati tawọn asofin agba to lọ nirọwọ rọsẹ lawọn agbegbe kan ni orilẹede naijiria, ni ko ri bẹẹ lawọn agbegbe miran, nitori isẹlẹ idaluru, jiji apoti ibo gbe ati itajẹsilẹ.

Gẹgẹbi awọn akọroyin BBC to tọpinpin bi eto idibo naa se lọ si yika orilẹede Naijiria ti wi, nkan ko fararọ lawọn agbegbe kan nilu Eko, Oyo, Ọsun, Rivers ati Anambra.

Ni agbegbe Agọ Palace, Ọkọta nilu Eko, rogbodiyan to waye nibẹ mu ẹmi eeyan kan lọ, ti ọ̀pọ ibo ti wọn di lawọn agọ idibo to wa nibẹ si sofo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Damilọla Ajayi: Ọ̀dá owó ló ṣún mi dé ìdí lílo ìyarun bíi fèrè

Koda, a tiẹ ri ibi ti wọn ti dana sun ọkada kan ati awọn iwe idibo, ti wọn si tun sọ ọkunrin kan ti wọn fẹsun kan pe oun lo wa nidi idaluru naa, ni oko pa.

Ni ipinlẹ Rivers bakan naa, ko din ni eeyan mẹẹdogun taa gbọ pe o gbẹmi mi lasiko rogbodiyan to waye lawn ọpọ agọ idibo to wa yika ipinlẹ ọhun.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni isoro ẹrọ kaadi to n yẹ orukọ awọn oludibo wo, to n se segesege gan tun da kun ọpọ isoro to wa nidi kudiẹkudiẹ to ba eto idibo naa.

Nigba to n fidi awọn isẹlẹ yii mulẹ, Kọmisana kan labẹ ajọ eleto idibo eyi to wa fun eto ilanilọyẹ awọn oludibo, Festus Okoye ni lootọ ni awọn gbọ nipa isẹlẹ yii.

Okoye ni iroyin ti de eti ajọ Inec lori bi wọn se n ji apoti idibo gbe ni agbegbe Akokotoro ati Bonny nipinlẹ Rivers, Eko ati ni Anambra.tawọn si n duro de abọ nipa isẹlẹ ọhun lati ọdọ awọn kọmisana fun ajọ eleto idibo lawọn ipinlẹ naa.

"Eto idibo lawọn agbegbe yii, paapa eto idibo sile asoju-sofin ati asofin agba ni ko lee waye, ti ajọ INEC yoo si pinnu to ba ya nipa akoko ti atundi ibo yoo waye lawọn agbegbe naa, lẹyin tawn ba ti gbọ ẹkunrẹrẹ alaye."