Nigeria 2019 Elections: Ọwọ́ ọlọ́pàá kò tíì tẹ àwọn jàńdùkú tó ṣiṣẹ́ náà
Ọwọ́ ọlọ́pàá kò tíì tẹ àwọn jàńdùkú tó ṣiṣẹ́ náà
Ipaya, ifooro ati ẹru nla lo ba awọn eeyan ilu Ijẹbu-Jẹsa, nijọba ibilẹ Oriade nipinlẹ Ọsun lasiko ti awọn janduku oloselu kan ba wọn lalejo ni oru ganjọ lẹyin idibo.
Gẹgẹ bi akọroyin BBC Yoruba to kan si ilu ọhun lẹyin rogbodiyan naa ti wi, deede aago mẹta oru ni awọn janduku oloselu naa ba ilu Ijẹbu-Jẹsa lalejo, ti wọn si n yinbọn takotako kaakiri.
Gbogbo awọn eeyan to sun lo dide, ti jinnijinni si da bo wọn lori ibusun wọn, ti wọn ko si lee jade.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- INEC kìlọ̀ fáwọn ọmọdé tó fẹ́ dìbò
- Ẹ̀yin jàǹdùkú olóṣèlú, ẹ so ewé gbéjẹ́ mọ́wọ́ - Ọ̀gá ọlọ́pàá
- Obasanjọ, Jonathan àti Abdulsalami dunnu sí bí ìbò ààrẹ ṣe lọ
- Ìtàn nípa bí ètò ìdìbò ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Nàìjíríà
- INEC yóò kéde àtúndì ìbò láwọn agbègbè kan torí rògbòdìyàn
- Èsì ìbò n jáde diẹ diẹ, APC ati PDP n fí àgbà hàn ará wọn
Awọn osisẹ eleto idibo to le ni igba to n sun lọwọ ni ileesẹ ajọ INEC to wa nilu Ijẹbu-Jẹsa si ni wọn dojukọ.
A gbọ pe ko si ọlọpaa tabi agbofinro kankan larọwọto eyi to mu kawọn janduku oloselu ọhun ri aye pa itu ọwọ wọn.
Igba wo ni ẹda yoo sinmi ogun ni Naijiria
Lẹyin ti wọn pari isẹ ibi ọhun tan, gbogbo aloku iwe idibo ni wọn sun gburu-gburu, to fi mọ awọn ohun eelo miran bii ẹni, ike iwẹ́ ati ẹrọ gẹnẹretọ meji.
Iroyin naa ni awọn agunbanirọ meji to tun jẹ osisẹ eleto idibo nibẹ, ni ọta ibọn ba.
Nigba to n fi idi isẹlẹ yii mulẹ, Kọmiṣọna fun ajọ eleto idibo nipinlẹ Ọsun, Olusẹgun Agbaje salaye pe, awọn osisẹ INEC ti ka ibo tan ki wọn to ko ẹru ti wọn lo pada si ijọba ibilẹ Oriade.
Bakan naa ni ọga ọlọpaa nipinlẹ naa Abiodun Ige fidi ọrọ naa mulẹ nigba ti o ba BBC Yoruba sọrọ.
Àwọn jàndùkú dáná sun ohun èlò ìdìbò l'Osun
Awọn agunbanirọ fara gbọgbẹ
"Idaji ti awọn osisẹ wa n ko ẹru ti wọn lo bọ wa si ijọba ibilẹ wọn, ni awọn eeyan kan n yinbọn soke, eyi to mu kawọn osisẹ ọhun juba ehoro. Awọn eroja bii ẹni, apoti ti wọn fi dibo ati ẹrọ amunawa nikan ni wọn wa ja silẹ."
Agbaje, lasiko to n fọwọ idaniloju sọya ni esi ibo ti de ibiti wọn ti n kojọpọ, isẹlẹ naa ko si lee sokunfa atundi ibo rara lagbegbe naa.
#NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí