NIgeria 2019 Election: INEC gba òṣùbà káre lórí àṣeyọrí ìdìbò

Goodluck Jonathan, Abdulsalami Abubakar ati Olusẹgun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Presidency

Àkọlé àwòrán,

Awọn aarẹ ana sọrọ lori eto idibo

Awọn olori orilẹede Naijiria tẹlẹri, Oluṣẹgun Obasanjọ, Goodluck Jonathan ati ajagun fẹyinti Abdulsalami Abubakar ti dunnu si bi idibo aarẹ ati tile aṣofin agba ṣe lọ.

Obasanjọ kọkọ koro oju si bi eto idibo ko tete bẹrẹ ni ibudo idibo ni gbogbo nnkan lọ nirọwọ 'rosẹ ni agboole Olusomi lagbegbe Ṣokori niluu Abeokuta to ti dibo.

Aarẹ ana rọ gbogbo awọn oludije lati gba esi ibo naa yala wọn jawe olubori tabi wọn fidi rẹmi.

Obasanjọ ni ẹnikan naa ni yoo bori ninu idije nigba ti ẹlomiran yoo fidi rẹmi.

Ninu ọrọ tiẹ, ajagun fẹyinti Abdulsalami Abubakar, lẹyin to dibo tan ni ibudo idibo Uphil Water Tank niluu Minna, rọ awọn oludije lati jẹ ki ifẹ orilẹede Naijiria wa lọkan wọn ṣaaju ohun kohun miran.

Àkọlé fídíò,

Damilọla Ajayi: Ọ̀dá owó ló ṣún mi dé ìdí lílo ìyarun bíi fèrè

Bakan naa ọgagun fẹyinti Abubakar ni ki awọn oludije gba esi ibo gẹgẹ bi amuwa Ọlọrun.

Abubakar tun gboriyin fajọ eleto idibo INEC lori bi o ti ṣagbatẹru eto idibo aarẹ ati tile aṣofin agba lọjọ Abamẹta kaakiri orilẹede Naijiria.

Aarẹ ana miran Goodluck Jonathan, to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP naa rọ awọn oludije lati fọwọ wọnu ti esi idibo ba jade.

Jonathan salaye pe eto idibo ni ọna kan gbogi ti awọn ọmọ Naijiria fi le yan adari rere.

Ọgbẹni Jonathan wa gbe oṣuba kare fun ajọ INEC fun iṣe takuntakun ti o ṣe lori eto idibo aarẹ ati tile igbimọ aṣofin agba.