Nigeria 2019 Election: Àwọn èsì ìbò tí n jáde diẹ diẹ

Aworan awọn eekan oloṣelu Naijiria

Esi idibo lawọn ibudo idibo ti n jade diẹ diẹ lẹyin ti wọn ti ka ibo lawọn ibudo idibo jakejado Naijiria.

Ninu awọn ibudo idibo ti akọrọyin BBC foju ri ibo kika, wọn jabọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ni wọn jijọ n fagba han ara wọn.

Saaju ki a to fi awọn esi ohun sọwọ, a fẹ ki ẹ mọ wi pe eyi ke ṣe akojọpọ esi ibo lapapọ, bi kii ṣe awọn esi to waye lawọn ibudo idibo awọn eekan oloṣelu ti a ṣe akojọpọ wọn paapa julọ ninu ibo Aarẹ.

Igbakeji Aarẹ Osinbajo fidirẹmi

Oríṣun àwòrán, @Yemi Osinbajo

Àkọlé àwòrán,

Igbakeji Yemi Osinbajo

Awọn oludibo to wa ni wọọdu idibo kẹrin, agọ idibo kẹtalelọgbọn ni agbegbe VGC, Lekki ikate ti igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo ti dibo,wọn ti fi ibo wọn da sẹria, ti ẹgbẹ PDP si bori APC nibẹ.

Ninu esi eleyi ti akọroyin wa jabọ lati ẹnu oṣiṣẹ Inec nibẹ, bayi ni nnkan ti ṣe lọ ninu idibo Aarẹ:

PYO Ward 4 unit 033 Esi ibo Aarẹ: ANN : 39, APC: 197, PDP: 384

Unit 033 A Esi ibo Aarẹ: ANN: 2, APC: 32, PDP: 41

Buhari na Atiku pẹlu ibo 19 lagọ idibo rẹ ni Yola

Oludije ipo Aarẹ fun ẹgbẹ APC, Muhammadu Buhari na fẹyin akẹgbẹ rẹ, Atiku Abubakar, to n soju ẹgbẹ PDP janlẹ ni agọ idibo Atiku pẹlu ibo mọkandinlogun.

Àkọlé àwòrán,

Aworan esi ibo aaye idibo Atiku

Buhari ri ibo 186 gba ni agọ idibo Ajiya unit 02 ni Yola, Adamawa nibit Atiku ti ri ibo 167 gba .

Atiku fẹyin Buhari gbol ni Aso Rock villa

Lẹyin ti wọn tun ibo ka ni agọ idibo to wa nile ijọba Presidential villa l'Abuja, apapọ esi ibo ni agọ idibo 021 ati 022 Aso Rock Villa lọ bayi:

Àkọlé àwòrán,

Buhari ati Atiku nibi ti wọn ti n dibo

Esi ibo Aarẹ APC - Buhari: 1017, PDP - Atiku: 1027,

Ile Asofin agba: APC 1009, PDP 1082

Donald Duke fidirẹmi lọwọ PDP lagọ idibo rẹ

Ibo mẹfa pere ni oludije ipo Aarẹ labẹ asia SDP, Donald Duke ri gba nibudo idibo rẹ

Atiku Abubakar, ti ẹgbẹ PDP lo jawe olubori mọ lọwọ.

Àkọlé àwòrán,

Egbe SDP niDonald Duke to ti jẹ Gomina ri n soju

Bi esi ṣe lọ ree ni agọ idibo rẹ tii ṣe AME Zion School unit 005 ni Calabar, ipinlẹ Cross River :

APC - Buhari: 98, PDP - Atiku: 291, SDP - Duke: 6

Saraki di aye idibo rẹ mu fun PDP

Bi nnkan ti ṣe lọ re agọ idibo Saraki Ajikobi ward, opobiyi PU 06 :

Esi Ibo Aarẹ APC 152, PDP 234, GPPN 1, AA 1, PCP 3