Election Update 2019: APC fá gbogbo ìbò tó pọ̀ jù fún ilé aṣòfin Ekiti

Ipinlẹ Ekiti
Àkọlé àwòrán,

Ipinlẹ Ekiti

Àjọ elétò ìdìbò INEC ti kede pe awọn oludije ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori fun aga mẹtẹẹta ti ile igbimọ aṣofin agba ati gbogbo aga mẹfa ile igbimọ aṣojuṣofin ipinlẹ Ekiti.

Gẹgẹ bi ajọ INEC ṣe kede rẹ, Ọmọọba Dayo Adeyeye ti APC ni wọn kede gẹgẹ bi ajawe olubori ni ẹkun idibo Guusu Ekiti.

Bakan naa, ọmọ ile igbimọ aṣojuṣofin ẹgbẹ APC kan ni aarin gbungbun Ekiti, Họnọrebu Ọpẹyẹmi Bamidele lo jawe olubori fun ipo Sẹnetọ.

Bamidele to jẹ ọmọ ile aṣoju ṣofin tẹlẹ laarin ọdun 2011 si 2015 gba a mọ oludije ti PDP, Obafẹmi Adewale lọwọ.

Lara awọn adari ajọ INEC, Ọjọgbọn Laide Lawal lo kede esi yii lowurọ ọjọ aiku ni ilu Ikere.

Yatọ fun APC ati PDP, awọn ẹgbẹ oṣelu mii to dije ni Democratic Alliance (DA), Green Party of Nigeria (GPN), Peoples Party of Nigeria (PPN), NAC atawọn ẹgbẹ mii.

Bakan naa ni adari ajọ INEC mii, Ọjọgbọn Abayọmi Fasina nipinlẹ naa kede Sẹnetọ Adetunmbi ti APC gẹg bi ẹni to jawe olubori ni ẹkun idibo ariwa Ekiti.

Ẹwẹ, awọn oludije APC ni ẹkun idibo Guusu Ekiti ati ariwa Ekiti keji, Yemi Adaramodu ati Olarewaju Ibrahim naa ni wọn kede ti wọn si laami laaka pẹlu alafo to pọ jọjọ.

Àkọlé fídíò,

Adedoyin: Tí mo bá rí Buhari, màá sọ fun kó rántí pé Ọlọ́run wà

Oludije APC ni ẹkun idibo ariwa kinni, Ọgbẹni Peter Owolabi fidi alatako rẹ, Kehinde Agboola ti PDP janlẹ.

Si eyi, Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi kan sara si esi idibo naa to ṣ'ọmọ 're fun gbogbo oludije ile aṣofin lẹgbẹ oṣelu rẹ.