Election Update 2019: Malaye padà sílé aṣòfin àgbà fún sàá kejì

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye/twitter
Ijọba ibilẹ meje lo wa ni ẹkùn idibo Iwọ oorun Kogi ti Melaye yoo tun pada lọ ọ ṣoju nile aṣofin agba
Sẹnetọ Dino Melaye ti jawe olubori ninu eto idibo gbogboogbo lati ṣoju ẹkùn idibo Iwọ oorun Kogi nile aṣofin agba Naijiria.
Sẹnetọ naa to dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, fi ẹyin alatako rẹ gboogi, Smart Adeyẹmi ti ẹgbẹ oṣelu APC janlẹ.
Melaye ni apapọ ẹgbẹrun marunlelọgọrin ati irinwo din maarun ibo lati fi bori alatako rẹ to ni ibo ẹgblrun mẹrindinlaadọrin ati mejilelẹẹdẹgbẹerun.
Moses Melaye: Dino Melaye sùn ìta gbangba mọ́jú níléesẹ́ DSS
Ijọba ibilẹ meje lo wa ni ẹkùn idibo Iwọ oorun Kogi ti Melaye yoo tun pada lọ ọ ṣoju nile aṣofin agba:Lokoja, Kogi/Koton Karfe, Kabba/Bunu
Ijumu, Yagba East ati Yagba West. Malaye si jawe olubori ninu mẹfa lara wọn.
Bi awọn esi ibo naa ṣe ri niyii:
Lokoja LGA
PDP = 24576
Yagba East LGA
PDP = 8638
APC = 5077
Mopa Amuro LGA
PDP = 5112
APC = 3658
YAGBA WEST LGA
PDP 8942
APC 6799
IJUMU LGA
PDP 11,749
APC 8,517
KABBA BUNU LGA
APC 8,971
PDP14, 756
Kogi LGA
APC 15,728
PDP 11,622
Ṣẹnetọ naa ti ki ara a rẹ ku oriire lori Twitter.