Election Update 2019: Ta a ni Kọla Balogun tó já ipò sẹ́nétọ̀ gbà lọ́wọ́ Ajimọbi?

Kola Balogun

Oríṣun àwòrán, Kola Balogun

Wọn bi Kọlawọle Mohammed Balogun ni ọjọ kẹtalelogun oṣu Keje, ọdun 1956 ni agboole Olubadan Ali-Iwo niluu Ibadan.

O kẹkọ gboye imọ ijinlẹ akọkọ ati ti Ọmọwe ninu imọ oṣelu ni Fasiti North Texas, Denton Texas, nilẹ Amẹrika.

O ti wa ninu oṣelu lati nkan bi ọdun 1980, bẹrẹ pẹlu ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP.

O jẹ oye oludari eto ẹnawo ati amojuto fun igbimọ ipolongo ibo fun Dokita Abubakar Oluṣọla Saraki.

Bakan naa lo jẹ kọmisana fun akanṣe iṣẹ ati eto irinna nipinlẹ Ọyọ labẹ gomina Adebayọ Alao Akala lọdun 2006.

O tun jẹ kọmisana fun eto okoowo ati ẹgbẹ alajẹṣẹku nipinlẹ Ọyọ lọdun 2007 si 2011.

O dije dupo sẹnetọ labẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party.

Àkọlé fídíò,

Nigeria 2019 Elections: Àwọn ẹbí rẹ̀ ní àwọn agbébọn tó ya wọ àgọ́ ìdìbò ló ta á níbọn

Ninu eto idibo naa to waye lọjọ kẹtalelogun oṣu Keji, ọdun 2019, Kọla Balogun ni ibo ẹgbẹrun lọna marunlelọgọrun ati okoolelẹẹdẹgbẹrin o din mẹrin, (105,716), ti Abiọla Ajimọbi si ni ibo ẹgbẹrun mejilelaadọrun ati okoolerugba o din mẹta.