Election Update 2019: Àwọn ohùn tó yẹ kí ẹ mọ nípa Oloriegbe tó rọ́pò Saraki

Aworan Ibrahim Oloriegbe

Oríṣun àwòrán, Facebook/oloriegbe4senate

Àkọlé àwòrán,

Mo wa lati wa tu awọn eeyan mi silẹ loko ẹru ni

Ajọsepo Ibrahim Oloriẹgbẹ ati Bukọla Saraki ko ṣẹṣẹ bẹrẹ.

Fun awọn ti wọn gbọ orukọ rẹ fun igba akọkọ nigba ti wọn kede rẹ pe o fidi Seneto Bukola Saraki rẹmi, ninu idibo asofin agba, o ṣeeṣe ki wọn maa bere pe tani Oloriegbe yi gaa an?

Ohun to han si ọpọ eeyan ni pe oludije egbẹ oṣelu APC nii ṣe ti o si jẹ ọmọ bibi ilu Ilorin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Adedoyin: Tí mo bá rí Buhari, màá sọ fun kó rántí pé Ọlọ́run wà

Amọ saaju idije ati esi tawọn eeyan n jaran rẹ lẹnu, awọn nnkan miran wa nipa rẹ ti o yẹ ki a mọ.

Kii ṣe akọkọ re ti yoo koju Saraki

Awọn mejeeji ti kọkọ koju ara wọn lọdun 2011 nigba ti Saraki bẹrẹ irinajo rẹ gẹgẹ bi asofin agba.

Aburo Bukola Saraki, Sẹnẹto Gbemi Saraki lo ṣẹṣẹ pari saa rẹ gẹgẹ bi Senẹtọ ti awọn mejeeji sijọ du ipo naa.

Labẹ asia ẹgbẹ ACN ni Oloriẹgbẹ́ ti dupo amọ Saraki to wa ni PDP nigba naa fẹyin rẹ janlẹ.

Oloriegbe ko ṣeṣẹ ma ṣe olori, O jẹ olori ile asofin Kwara nigba kan ri

Laarin ọdun 1999 si 2003, Ibrahim Oloriegbe jẹ olori awọn ọmọ ẹgbẹ to pọju lọ nile asofin ipinlẹ Kwara.

O tun joye alaga igbimọ ile to n mojuto ọrọ ilera ati eyi to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ.

Lẹyin to pari nile asofin ko ti di ipo oṣelu kankan mu mọ lati igba naa.

Àkọlé fídíò,

Nigeria 2019 Elections: Àwọn ẹbí rẹ̀ ní àwọn agbébọn tó ya wọ àgọ́ ìdìbò ló ta á níbọn

Oloriegbe loun wa tu ara Ilorin silẹ loko ẹru ni

Koko pataki kan ti Ibrahim Oloriegbe dimu, ninu ipolongo rẹ ni pe oun wa lati wa tu awọn ara ilu Ilorin silẹ loko ẹru ni.

Ninu ọpọ ifọrọwanilnuwọ to ṣe pẹlu awọn akọroyin, kii ma salai tẹnumọ pe, iṣẹ ati oṣi to pọ nilu jẹ ohun kan gboogi ti oun yoo fopin si, bi oun ba de ipo asofin.

Lọdun 2018, ijọba apapọ sọ pe awọn pin biliọnu meji naira fun awọn mẹkunu tole ni ẹgbẹrun mẹrinla lati ọdun 2014, labẹeto gbọnṣẹ gbọnyanu wọn, National Conditional Cash Transfer Programme.

O wa lara awọn to da APC silẹ ni Kwara.

Iriri to to ọgbọn ọdun ni Dokita Ibrahim Oloriẹgbẹ ni, ninu eto iṣakoso lẹka ijọba ati gẹgẹ bii aladani.

Amọ Irinajo to gbe de ipo yii lagbo oṣelu lawọn eeyan yoo ma fi ranti rẹ.

O ti bẹrẹ oṣelu ti pẹ, ti a si ri ka ninu akọsilẹ pe, o wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ ACN ti wọn jijọ darapọ mọ awọn ẹgbẹ oṣelu miran, to da APC silẹ nipinlẹ Kwara.