Saraki kò fi ipò kẹta tó dìmú ṣèlú l‘óore ní Kwara - Aráàlú faraya
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Election Update 2019: Aráàlú ní ẹ́yìn lílọ Saraki, Kwara yóò ṣún síwájú ni

BBC Yorùbá lọ yíká ìgboro ìlú Ilọrin, láti mọ ipa tí ìfìdírẹmi ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Bukọla Saraki nínú ìbò sílé aṣòfin àgbà, yóò ní lórí àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó bá wa sọ̀rọ̀ ló ní, kò sí àdánù kankan tí ìpínlẹ̀ Kwara yóò rí, nítorí pé Saraki kò di ipò kẹta mú mọ́ ní Nàíjíríà.

Wọ́n ní ara Saraki nìkan ló ń fi ipò náà tọ́jú, tí ìlú kò sì mọ ipa rẹ̀ lára.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn míràn ní, àwọn yóò mọ ìfìdírẹmi Bukọla Saraki lára, torí ọmọ ìpínlẹ̀ Kwara kò ní sí ní ipò kẹta mọ́ nínú àkóso Nàíjíríà.

Wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Saraki ṣe afárá olókè sí ìlú lásìkò tó wà nípò, èyí tó jẹ́ àǹfààní fún ìlú.