2019 elections update: PDP pè fún ìwọ́gilé èsì ìdìbò ààrẹ ní ìpínlẹ̀ mẹ́rin

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar

Àkọlé àwòrán,

PDP fẹ̀sùn kan àwọn agbófinró àti INEC lórí ìdìbò ààrẹ àti ilé aṣòfin àpapọ̀

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti pe fun iwọgile awọn esi idibo aarẹ lati ipinlẹ Zamfara, Nasarawa, Bornu ati Yobe.

Ẹgbẹ oṣelu PDP pe ipe yii nibi ipade kan ti wọn ṣe pẹlawọn oniroyin ni alẹ ọjọ iṣẹgun ni ilu Abuja.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ṣalaye pe ni ipinlẹ Yobe iye awọn eeyan to dibo pọ ju iye awọn oludibo ti wọn forukọ silẹ ni ipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kabiru Taminu Turaki to jẹ igbakeji oludari agba igbimọ ipolongo PDP ṣalaye pe nipasẹ ofin eto idibo orilẹede Naijiria, iru ibo bẹ ko lẹsẹ nlẹ.

O sọ siwaju sii pe ni ipinlẹ Zamfara, ko si idibo kọkan nibẹ nitori ko si awọn iwe akọsilẹ esi idibo ni eyikeyi awọn ibudo idbo to wa kaakiri ipinlẹ naa.

Wọn ni awọn esi idibo to wa lati ipinlẹ naa jẹ eyi ti awọn oṣiṣẹ ajọ INEC kan gbe kalẹ gẹgẹ bii idari awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Atiku abubakar

Àkọlé àwòrán,

PDP pe fun iwọgile esi idibo aarẹ ni Zamfara, Plateau,Abuja ati Yobe

O fi kun un pe ni ipinlẹ Borno, n ṣe ni awọn eeyan kan joko gbe esi didibo naa kalẹ nibẹ nitori gẹgẹ bi o ṣe wi, 'Ko si idibo nibẹ'

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu PDP tun beere fun ibo rẹ to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọgọjọ nipinlẹ Nasarawa ati mọkandinlọgọrin ibo ni ipinlẹ Kogi to ni INEC wọgile lọna ti ko bofin mu.

Ẹgbẹ PDP tun mẹnu ba ipinlẹ Plateau, olu ilu ilẹẹwa Abuja gẹgẹ bii ara awọn ipinlẹ ti INEC ti wọgile, tabi yọ ninu ibo wọn.

Àkọlé fídíò,

Election Update 2019: Lẹ́yìn lílọ Saraki, Kwara yóò ṣún síwájú ni

O wa ke si ajọ INEC lati ko awọn iroyin inu ẹrọ ayẹwo kaadi idibo rẹ sita fun araye, paapaa julọ awọn ẹgbẹ oṣelu to kopa, lati yẹwo.

PDP ko tun ṣai fi ẹsun kan awọn ileeṣẹ agbofinro ati alaabo pe wọn ṣe agbodegba fun ẹgbẹ oṣelu APC lati 'tẹ ifẹ araalu mọlẹ' lasiko idibo naa.