Nigeria Election 2019: Saraki àti àwọn sẹ́nẹ́tọ̀ tó fẹ̀yìn gbálẹ̀ nínú ìdìbò ilé aṣòfin

Bukola Saraki Image copyright Senate
Àkọlé àwòrán Saraki kuna ninu ibo ile aṣofin

Esi idibo gbogbogbo orilẹede Naijiria jẹ iya lẹnu papaa julọ idibo ile aṣofin agba l'Abuja.

Olori ile igbimo aṣofin l'Abuja Bukola Saraki ati awọn gbajugbaja sẹnẹtọ kan ko ni lanfani lati pada sile mọ lẹyin ti wọn fidi rẹmi ninu idibo ọjọ ile aṣofin ọjọ Abamẹta.

Saraki to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lo n ṣoju ẹkun arin gbungbun ipinlẹ Kwara nile aṣofin agba l'Abuja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionElection Update 2019: Lẹ́yìn lílọ Saraki, Kwara yóò ṣún síwájú ni

Ṣugbọn Saraki ko ni le pada sile aṣofin lẹyin ti Ọmọwe Ibrahim Oloriegbe to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC fagba han an ninu idibo ọjọ Satide.

Saraki darapọ mọ PDP lati APC, o si ni ijakulẹ ninu idibo abẹle PDP fun ipo aarẹ eleyi ti Atiku Abubakar ti jawe olubori.

2. Abiọdun Olujinmi:

Image copyright Abiodun Olujinmi

Sẹnetọ̀ to n soju ẹkun idibo Guusu Ekiti, to tun jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu PDP, Abiọdun Olujinmi, naa ko lee pada sile asofin agba mọ̀.

Idi ni pe o fidi rẹmi ninu ibo ile asofin agba to waye lọjọ Satide.

Olujinmi ni olori ọmọ ẹgbẹ oselu to kere julọ nile asofin apapọ ilẹ wa lọwọ lọwọ bayii.

3.Godswill Akpabio

Image copyright Nigerian Senate
Àkọlé àwòrán Akpabio fẹyin gbo lẹ ninu idibo ile aṣofin

Sẹnẹtọ mii ti ko tun wọle ni Godswill Akpabio to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC o n ṣoju ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Akwa Ibom.

Akpabio to jẹ Gomina ipinlẹ Akwa Ibom tẹlẹ ri fidi rẹmi ninu idibo ti igbakeji gomina ipinlẹ ọhun tẹlẹ ri Christopher Ekpenyong tii ṣe ọmọ ẹgbẹ PDP ti jawe olubori.

Akpabio ni abẹnugan ẹgbẹ oṣelu alako nile aṣofin agba ṣugbọn o kọwe fipo naa silẹ nigba to darapọ mọ ẹgbẹ APC lati PDP.

Shehu Sani

Image copyright Nigerian Senate
Àkọlé àwòrán Shehu Sani fidi rẹmi

Ṣẹnẹtọ Shehu Sanni jẹ ọkan lara awọn alẹnulọrọ nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja.

Oun lo n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Kaduna, ṣugbọn o fidi rẹmi ninu ibo ọjọ Satide.

Uba Sani to dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC lo wọle idibo naa. Ẹgbẹ oṣelu APC lo gbe Shehu Sanni gẹgẹ bi sẹnẹtọ.

Ṣugbọn o darapọ mọ ẹgbẹ osẹlu PRP lẹyin to fidi rẹmi ninu ibo abẹle APC.

Binta Masi Garba

Image copyright Nigerian Senate
Àkọlé àwòrán Binta Masi Garba padanu

Binta Masi Garba ni sẹnẹtọ obinrin kan ṣoṣo to to wa lati ariwa orilẹede Naijiria.

Oun lo n ṣoju ẹkun ariwa ipinlẹ Adamawa, o si jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Ishaku Cliff to jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP lo fẹyin rẹ gbo lẹ ninu idibo ile aṣofin agba to waye lọjọ kẹtalelogun oṣun keji.

Andy Ubah

Image copyright Nigerian Senate
Àkọlé àwòrán Andy Uba padanu ibo

Sẹnẹtọ Andy Ubah n ṣoju ẹkun gusu ipinlẹ Anambra nile igbimọ aṣofin agba.

Ubah to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ko ni le pada sile mọ lẹyin idibo gbogbogbo lẹyin Ifeanyi Ubah, ọmọ ẹgbẹ YPP fagba han an.

Ifeanyi Ubah ni sẹnẹtọ akọkọ ti yoo wọle labẹ asia ẹgbẹ YPP.