Ibikunle Amosun- Ẹgbẹ́ onípákí ni kí ẹ dìbò fún Gómìnà nìpínlẹ̀ Ogun

Aworan Gomina Ibikunle Amosun Image copyright @Ibikunle Amosun
Àkọlé àwòrán Mo fẹ ki ẹ jade dibo fun oludije ẹgbẹ APM

Gomina Ibikunle Amosun ti salaye lẹkunrẹrẹ ohun ti o wa nidi aawọ to n fa ipinya ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti o ṣe lọjọbọ ti wọn fihan lori ẹrọ ayelujara,Amosun ni awọn to wa lati Abuja lasiko idibo abẹnu ẹgbẹ APC lo da wahala silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ.

Amosun to wọle gẹgẹ bi Sẹnẹtọ labẹ ẹgbẹ APC ninu idibo ile asofin to waye wa rọ awọn alatilẹyin rẹ lati dibo fun Adekunle Akinlade ti ẹgbẹ APM gẹgẹ bi Gomina.

''Mo dupe fun bi ẹ ṣe di ibo aarẹ gbe Aarẹ Buhari wole ṣugbọn ni ti Gomina to n bọ lọna yii, ẹgbẹ paki ni ki ẹ di ibo Gomina yin fun''

Amosun ni ohun fa awọn to wa nidi dida ipinlẹ Ogun ru le Olorun lọwọ ti o si rọ awọn agba oṣelu ilẹ kaarọ o jiire lati kiye sara ki ẹgbẹ APC ma baa fidirẹmi.

''Ṣebi ẹ ri bi ibo ti ṣe lọ lawọn ipinlẹ kaarọ ojiire lasiko ibo aarẹ, bi a ko ba duro sinsin, o ṣeeṣe ki a fidirẹmi''.

APM ni ẹgbẹ ti a n ṣe bayi ni ipinlẹ Ogun

Ni idahun si ibeere pe bawo ni ohun ṣe wa ninu ẹgbẹ APC ti o si ni ki awọn eeyan dibo fun oludije ẹgbẹ APM, Gomina Amosun ṣalaye pe wọn fi eru gba ibukun lọwọ Adekunle Akinlade ni.

''Ogun West la ti jijọ sadehun pe a o fun ni ipo Gomina ti gbogbo wa si ti faramọ. Ṣugbọn nigba ti awọn to ti lọ lati ọdun mẹrin sẹyin pada de lati Abuja, niṣe ni wọn da ọrọ ru''

O fi akawe ọrọ awọn obinrin meji ti wọn ja si ọmọ ninu bibeli kin ọrọ rẹ lẹyin ti o si ni awọn yan an ni ki Adekunle Akinlade lọ si ẹgbẹ APM nitori ki ẹgbẹ ma bajẹ ni.