Election Update 2019: Àwọn ọlọ́pàá dá ìpàdé àwọn alátakò Tinubu dúró l'Eko

Asiwaju Bola Tinubu Image copyright Facebook/Tinubu
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori ibo gomina nipinlẹ Eko

Awọn ọlọpaa yabo ile itura Airport Hotel ni Ikeja nipinlẹ Eko nibi ti awọn ajijagbara olosẹlu kan ti n ṣe ipolongo ibo lati ta ko Asiwaju Bola Tinubu ṣaaju ibo gomina ọjọ Abamẹta ọsẹ to n bọ.

Awọn ajijagbara ọhun ti orukọ wọn n jẹ Orange Movement wa ni gbọngan Oramiyan ninu ile itura ọhun nibi ti iroyin ni wọn ti n gbero lati ta ko erongba Tinubu ninu idibo gomina to n bọ ni ipinlẹ Eko.

Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Orange Movement sọ fun awọn oniroyin pe awọn ọlọpaa ni pe ẹgbẹ naa ko gbaaye lati ọdọ awọn alaṣẹ ki wọn to sẹ agbekalẹ eto ti wọn ṣe nibẹ.

Àdéhùn èmi àti Ọlọ́run ni pé èèyàn láti Yewa yóò jẹ́ Gómìnà -Amosun

Àwọn oun àjòjì tó ṣẹlẹ̀ nígboro níbi àjọyọ̀ ìṣẹ́gun Buhari

Àwọn kókó márùn-un tí ìdìbò ààrẹ Naijiria kọ́ wa

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWale Ahmed: APC kò ṣe mọ̀dàrú, PDP ló fẹ́ gbà'jọba tipátipá

Babajide Sanwo-Olu to n dije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ni Tinubu n ṣe atilẹyin fun ninu ibo gomina ọsẹ to n bọ.

Awọn alako Tinubu ati awọn ọmọ oṣelu PDP kan ṣalaye pe saa karun un ni yoo jẹ fun Tinubu ti ẹgbẹ APC ba tun wọle ninu ibo gomina to n bọ nipinlẹ Eko.

Ẹgbẹ Orange Movement ti bẹrẹ si ni pariwo ''O to gẹ'' iru orin ti wọn kọ abẹnugan ile aṣofin agba l'Abuja, Bukola Saraki ko to fidi rẹmi ninu ibo ile aṣofin agba ọjọ kẹtalelogun oṣu Keji.