Election Update 2019: Kínni àwọn oun tí ìdìbò ààrẹ Naijiria kọ́ wa?

Arakunrin kan n ka iwe iroyin to fi esi idibo Naijiria han ni ilu Kano Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Isegun Buahari lo gba awọn iwe iroyin kan

Aarẹ orilẹede Muhammadu Buhari ti jawe olu bori ninu idibo aarẹ ti yoo fun laanfani lati ṣe ijọba fun saa ọlọdun mẹrin miiran.

Alatako rẹ to gbe ipo keji, Atiku Abubakar, ti ni idojuti nla fun Naijiria ni esi idibo naa ati wipe oun yoo gbe ọrọ naa lọ ile ẹjọ.

Amọ ṣa bi awọn kan ti ṣe n dunnu si ibo naa ti awọn miran si n fapajanu, a ni ki a ṣe agbeyẹwo awọn oun marun-un ti idibo naa fi han wa ti o mu lamilaka.

1. Ó yátọ̀ sí ti àtijọ́ gedegbe,bó tilẹ̀ jẹ́ pe ohun to mu iyatọ yi wa kii ṣe oun to dára

Pupọ lo fi orukọ silẹ lati kopa ninu idibo yi .Koda akọsil fi han wa pe eeyan mẹtalelaadọrin ni o laanfani lati dibo.

Ohun ti eyi si tọka si ni pe idibo Naijiria leyi to ni oludibo to pọju lọ ni Afrika.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWale Ahmed: APC kò ṣe mọ̀dàrú, PDP ló fẹ́ gbà'jọba tipátipá

O ṣe ni laanu pe ida mẹta ninu awọn oludibo to forukọ le lo jade wa dibo.

Idibo gbogbogbo 2019 lo ri oludibo to kere ju lati ogun ọdun ti Naijria ti pada si ijọba awa arawa.

Ati ọdun 2003 ni iye awọn oludibo ti n kere si ni orilẹede yii.

2. Eniyan ńlá ṣì ni Buhari ni òkè ọya

Atiku Abubakar to ṣe ipo keji ninu idibo aarẹ ni jibiti wa ninu akojọ esi ibo naa.

O ni o yani lẹnu wipe akojọ ibo ni awọn agbegbe ti oun ti ni okiki ju bii Ipinlẹ Akwa Ibom fi bi ilaji kere ju ti 2015

Ẹkọ ta ri kọ ni pe Buhari ni atilẹyin to pọ ni Ariwa Naijiria nibi ti wọn ṣi ri bi eniyan rere.

Lati bi idibo marun sẹyin ni iye awọn oludibo rẹ ti pọ.

Awọn oludibo ko jade to ni Guusu Naijiria nibi ti Atiku ro pe o yẹ ki iye awọn to dibo fun oun pọ. O bori ni Guusu Naijiria ṣugbọn iye ibo to fi bori ko to lati koju miliọnu mẹrin ti Buhari fi wọle.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Atiku Abubakar ti kọ esi idibo naa

3. Wahala ọrọ aabo ko di awọn alatilẹyin Buhari lọwọ lati dibo

Atiku ti beere pe bawo lo ṣe jẹ ti awọn agbegbe oke ọya nibi ti ọrọ aabo ti jẹ ipenija ṣe ni awọn oludibo to pọ.

Ipinlẹ Borno ati Yobe jẹ awọn ipinlẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC ti ri ọwọ mu daada. Atilẹyin wọn ko ti i dinku bo tilẹ jẹ wipe aisi aabo ti le miliọnu meji eniyan kuro lagbegbe naa.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ko ni si aworan awọn oludije fun ọdun mẹriin miiran

4. Isunsiwaju idibo ṣe ijamba fun alatilẹyin awọn oludije mejeeji to lewaju

Bi ajọ INEC ṣe sun idibo si iwaju pẹlu ọsẹ kan mu inu bi ọpọ ọmọ Naijiria eyi to ṣe okunfa ki awọn kan ma fẹ rin irinajo lẹẹmeji lati le wa dibo.

Awọn oludije mejeeji ni ọrọ yii ṣakoba fun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajọ Inec ni ipolongo ọjọ idibo saaju ọdun naa yoo mu idagbasoke ba eto oselu lorilẹede Naijria

5. Idibo pẹlu ẹrọ igbalode lo dara ju.

Awọn onwoye kan sọ pe, ẹrọ igbalode ko ni jẹ ki awọn kan ṣe aṣiṣe to pọ, ko si ni jẹ ki awọn kan le yi ibo.

Bo tilẹ jẹ pe ẹrọ ti wọn fi n yẹ orukọ wo ṣe ṣegeṣege ni awọn ibi kan, ẹrọ igbalode lo le fi ifẹ awọn eniyan han, ti yoo si foju magomago han.