NBC ní kí àwọn ilésẹ to tẹ ofin lóju san #500,000

Image copyright NBC
Àkọlé àwòrán 2019 Elections: NBC na ilí iṣẹ́ ìròyìn 45 ní pàsán

Ile ise iroyin marundinlaadota ni ajọ NBC ni ko sanwo ìtanran fún àwọn aṣe máse tó wáye lásiko ìdìbò gbogboogbo tó wáye lọ́jọ́ kẹtalélógún oṣu tó kọja.

Awọn ile iṣẹ iroyin tí igbá ọ̀rọ̀ náà kan náà ṣí mọ lóri ni Channels, TVC, NTA, AIT, Vision Fm, Arewa radio, Radio Lagos àti àwọn míràn.

Image copyright Nbc
Àkọlé àwòrán 2019 Elections: NBC na ilí iṣẹ́ ìròyìn 45 ní pàsán
Image copyright Nbc
Àkọlé àwòrán NBC ní kí àwọn ilésẹ ti tẹ ofin lóju san #500,000

Gẹgẹ bi olorí àjọ náà Mallam Modibo Kawu ni gbogbo àwọn ile iṣẹ́ yìí ni yóò fi ẹgbẹrun lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta naira jura.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYinka Ajia: ìbẹ̀rù Ọlọrun ni mo fẹ́ fi tukọ̀ Kwara ti mo ba wọlé

O ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilanilọyẹ ni àjọ oun ti ṣe láti ri dáju pẹ ẹnikẹni ò tẹ ojú òfin mọ́lẹ̀, sùgbọn o ṣe ni láànú pé gbogbo rẹ̀ pàbó ló jási lásiko ìdìbọ ààrẹ tó wáye ní ọjọ kẹtàlélogun osu kéji.

O ní ẹsẹ ti àwọn ile iṣẹ yii sẹ jẹ oríṣiriṣi, sùgbọn kò kéré sí àwọn ilé ìròyìn tó wọn jẹ ki wọn fi ilé iṣẹ́ wọn tẹ́ pẹpẹ èèbu àti sisọ àwọn ọ̀rọ̀ alufansa.

O fi kún pé àwọn ile iṣẹ́ Radio mi fààyè gba ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ tó lé dá rògbòdiyàn sílẹ̀ láwùjọ.