Nítorí ìwọ́de, Amosun àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC tutọ́ síra wọn lójú nípínlẹ̀ Ògùn

Ibikunle Amosun Image copyright Amosun ibikunle
Àkọlé àwòrán NLC fẹ́ ṣe ìwọ́de nítorí àìsan owó òṣìṣẹ́, ṣùgbọ́n gómìnà Amosun ní kò sóhun tó jọọ́

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ṣi wa lẹnu ileri 'bi ikun lo loko, bi pakute ni'.

Ọrọ lori iwọde tawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ n gbero lati ṣe ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun un, oṣu kẹta, ọdun 2019 ni ilu Abẹokuta.

Awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun pẹlu atilẹyin awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ naa lorilẹ-ede Naijiria n leri ati gunle iwọde nitori owo oṣu oṣiṣẹ ati oṣiṣẹfẹyinti nipinlẹ naa eyi ti wọn ni o ti wọ ọdun mẹjọ bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIssa Aremu: ṣàlàyé kíkún nípa èròńgbà ẹgbẹ́ Labour to bá jáde

Amọṣa, gomina Ibikunle Amosun ti fesi ṣaaju pe oun yoo yẹyẹ awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ to ba gbiyanju tabi san aṣọ bẹẹ ṣoro ni ipinlẹ naa.

Nibayii, aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC lorilẹ-ede Naijiria, Ayuba Wabba ati igbimọ iṣakoso apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹ-ede Naijiria ti ranṣẹ pada si gomina Amosun pe awọn ti gbọ ohun to sọ o, ṣugbọn apo ara rẹ lo sọ ọ si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYinka Ajia: ìbẹ̀rù Ọlọrun ni mo fẹ́ fi tukọ̀ Kwara ti mo ba wọlé

"A fẹ fi da aloju pe ihalẹ rẹ ko lee tu irun kan lara erongba wa lati dide daabo bo awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ Ogun ti wọn n tẹ ẹtọ wọn mọlẹ baṣubaṣu."

"Awọn ohun to kan wa ju ni aisan awọn owo ti wọn yọ ninu owo oṣu awọn oṣiṣẹ fun ifẹyinti, alajẹṣẹku, ọdun ileya, keresi ati bẹẹbẹẹlọ fun oṣu marunlelọgọrun lai san an pada fawọn oṣiṣẹ."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí