Ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí IS yọ Al-Barnawi ọmọ olùdásílẹ̀ Boko Haram nípò gẹ́gẹ́ bíi adarí ISWAP

Abu Musab Al-Barnawi tó jẹ ọmọ oludasile Boko Haram Image copyright LeBabi.net
Àkọlé àwòrán Abu Musab Al-Barnawi ni akọbi ọmọ Mohammed Yusuf, iyẹn oludasile Boko Haram ti wọn pa ni ọdun 2009.

Ẹgbẹ agbesunmọmi Islamic State ti yọ Abu Musab Al-Barnawi, to jẹ adari ẹka IS to wa ni iwọ oorun Afrika, ISWAP kuro nipo.

Ahmad Salkida kan, akọroyin ti awọn eniyan mọ gẹgẹ bii ọkan gboogi ninu ọmọ Naijiria to maa n ri aaye wọ ọdọ awọn adari ẹgbẹ Boko Haram lo ṣe ikede yii lori ayelujara Twitter ni ọjọ Aje.

Akọroyin naa ni Abu Abdullah Ibn Umar-Al-Barnawi ni wọn fi rọpo rẹ.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Salkida ni ẹgbẹ naa ko sọ idi ti wọn fi yọ Abu Musab nipo ninu igbohunsilẹ ti wọn ti ṣe ikede naa. Oun lo jẹ akọbi ọmọ Mohammed Yusuf, iyẹn oludasile Boko Haram ti wọn pa ni ọdun 2009.

ISWAP jẹ ọkan lara awọn ẹya Boko Haram. Ọdun 2005 ni Boko Haram dara pọ mọ IS nigba ti Abu Musab jẹ agbẹnusọ.

Akọroyin naa ni ko si oun to ṣe Abu Musab, ati wi pe o ṣi wa labẹ ISWAP bo tilẹ jẹ wipe wọn yọ ọ nipo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBuhari gbọ́dọ̀ yọ àwọn mínísítà tí kò wúlò ní sáà kejì yí-Ogundamisi