Kwara Bursary: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kwara Poly ṣèwọ́de fún owó ìrànwọ́ ẹ̀kọ́

Awọn akẹkọ ọmọ bibi ipinlẹ Kwara

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ileẹkọ gbogbonse Poly tipinlẹ Kwara, ti wọn jé ọmọ bíbí ìpínlè Kwara yà bo ileesẹ eto isuna ìpínlè náà (Kwara State Internal Revenue Service) láti béèrè fún owó iranwọ eto ẹkọ (Bursary) wọn.Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, to gbé ìwé ilewọ ati patako to ni akọle oríṣiríṣi lọ́wọ́, ni wọn n béèrè fún owó iranwọ náà, gẹgẹ bii ẹtọ wọn.

Awọn akẹkọ naa, Moshood Walik, lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ fi ẹṣun kàn ijọba ipinlẹ Kwara pe, o n fun awọn ni ẹgbẹrun marun naira pere fun owo iranwọ eto ẹkọ, to si tun ti pẹ tijọba ti san owo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agbẹnusọ fawọn akẹkọ naa ni ẹgbẹrun lọna ogun naira ni ijọba ipinlẹ Eko n san bii owo iranwọ eto ẹkọ fawọn akẹkọ rẹ, tijọba ipinlẹ Kwara ko si ranti awọn.

Wọn fikun pe lẹyin tawọn se iwọde lọsẹ to kọja, ijọba ipinlẹ Kwara gbe ogun miliọnu naira kalẹ fun sisan owo iranwọ eto ẹkọ naa amọ titi di asiko yii, awọn ko mọ ibi ti owo naa wọlẹ si mọ.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni, àwọn tí lọ sí ilé ìṣe tó wà fún eto isuna láti mọ nkan tó se okùnfà idiwo láti sàn owó naa, amọ gbogbo igbinyanju awọn nibẹ lo ja si pabo.

Ẹgbẹ awọn akẹkọ to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kwara wa n rọ awọn alasẹ ipinlẹ naa lati wa nkan se si ọrọ yii nitori iwọde awọn ko mu ija lọwọ.;