Oyo Election: Makinde ní ìpínlẹ̀ Ọyọ kò fẹ́ ajẹ́lẹ̀ mọ́

Oyo Election: Makinde ní ìpínlẹ̀ Ọyọ kò fẹ́ ajẹ́lẹ̀ mọ́

Oludije fun ẹgbẹ oselu PDP, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, dupẹ lọwọ awọn oludije fẹgbẹ oselu SDP, ADC ati ZLP ti wọn pinnu lati se atilẹyin fun oun.

Makinde ni gbogbo awọn oludije naa lo kunju iwọn ju oun lọ, ti oun yoo si se amusẹ gbogbo adehun tawọn dijọ fọwọsi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe ipinlẹ Ọyọ ko nilo ajẹlẹ mọ, ti wọn yoo si maa fi owo Ọyọ tọju awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ.

Makinde ni awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ko gbọdọ dibo fun Adebayọ Adelabu, tii se alatako rẹ latinu ẹgbẹ oselu APC, pẹlu afikun pe, ibo ti wọn ba di fun Adelabu dabi igba ti wọn dibo fun itẹsiwaju isejọba Abiọla Ajimọbi ni fun saa kẹta.