Olóyè Obasanjo: Ọmọ oko ní mí lara mi ṣe le koko
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere, ló jẹ ki ń lókun

Ààrẹ tẹ́lẹ̀ ní orílẹ̀èdè Nàíjíríà, Matthew Okikíola Arẹmu Olusegun Obasanjo, ti salaye pe koko ni ara ọta le fun oun, tori pe oun jẹ ọmọ oko.

Lásìkò tó ń bá BBC Yorùba sọ̀rọ̀, Ọbasanjọ ni kọ́rọ̀ òun tó dayọ, ojú ti rí, pàápàá jùlọ lásìkò ti òun wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

Lasiko to n sọ ohun ti oju rẹ ti ri lọgba ẹwọn, Obasanjo sàlàyé pé, òhun kò ni ìrètí mọ ninu ọgba ẹwọn, nítori àṣẹ Abacha ni pé afi ti òun ba kú ni òun àti àwọn méjì míràn to lé jáde lẹ́wọ̀n.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọbasanjọ ni riro ni ti eniyan lọrọ naa jẹ, tori sise ni ti Ọlọrun ọba, sùgbọ́n nípa ore ọfẹ́ Ọlọ́run, oun nìkan ni oun jáde laaye lọgba ẹwọn.

Obasanjo wá sàlàyé pé nígbà ti Ọlọ́run ti ṣe irú oore yìí fún oun, kò si ǹkankan to ku fun oun ju láti máa dúpẹ́ lọ.