Czech Republic: Takọ-tabo Kìnìún ni ọkùnrin náà ń sìn nínú àgò kanṣoṣo

PRASEK ÀTI KINIUN Image copyright ZDENEK NEMEC/MAFRA/PROFIMEDIA
Àkọlé àwòrán Czech Republic: Kìnìùn ṣe ikú pa olówó rẹ̀

Michal Prasek ni olóńgbò nla, eyiun kiniun to ti n sin fun ọdún mẹ́sàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aládugbò n ké gbàjarè lórí ọ̀rọ̀ náà tẹ́lẹ̀.

Bàbá Prasek yii lo sadede ri òkú ọmọ rẹ̀ nínú ilé kìnìún, to sí ké sí àwọn akọròyìn abẹ́le lati kede ohun to ṣélẹ̀ àti pé, ilẹkùn ilé kìnìún náà wà ni títì sínú.

Awọn ọlọpàá ti wọn pè wá wo ohun to ṣẹlẹ̀, kọ́kọ́ pa awọn ẹranko míràn to wà nínú àgò tó fara ti kìnìún náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agbẹ́nusọ ọlọpàá ní, pípa ti wọn pa àwọn ẹranko tó ku náà ṣe pàtàkì láti le kọja sọ́dọ̀ ẹni ti kìnìún pa.

Ọgbẹ́ni Prasek, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ra kìnìún lọ́dún 2016, o tún wa ra abo ni ọdun to kọja, to si kó àwọn méjèèjì pọ̀ sinu àgò kannáà lẹ́yìnkùlé rẹ ni abúle Zdechov.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSeyi Makinde: Màá fẹ́ káwọn aráàlú mọ ìpa ìjọba mi lára sí rere

Sáájú ní ìjọba ti kọ láti fun láàyè láti kọ́lé fún pé, ó ń sí eranko lọ́nà àìtọ́, sùgbọ́n èdè àìyedè bẹ́ sílẹ̀ nígbà to kọ̀ láti jẹ́ ki àwọn aláṣẹ̀ wọ inú ọgbà rẹ.

Sugbọn wahala bẹ silẹ nigba ti ẹnikan to n wa kẹkẹ sadede kọlu abo kiniun rẹ lasiko to n mu gba atẹgun lọ loju popo, to si fi okun si lọrun bii aja.

Nibayii, kiniun to n sin naa, lo papa san sọrun ọsan gangan.