Ọbasanjọ: N kò ní dẹ́kun láti máa tako Buhari

Buhari ati Ọbasanjọ nki ara wọn Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Ọbasanjọ ti kọ lẹta si Buhari eleyi to di gbajugbaja kaakiri agbaye

Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Olusegun Obasanjo ti ni, idi ti oun fi n tako Aarẹ Buhari ni wi pe isejọba tiwantiwa fayegba ki eniyan o sọrọ nipa ijọba to wa lode.

Aarẹ Obasanjo ni asiko to n se ayẹyẹ ọdun kejilelogun ni ilu abeokuta sọ wi pe ko si ija laaarin oun ati Aarẹ Muhammadu Buhari.

O ni isẹ ilu kii se ohun ti eniyan fi n se ibatan, amọ o nii se pẹlu titako igbesẹ ijọba ti ko ba ba awọn eniyan lara mu.

Ni ọpọ igba, Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Olusegun Obasanjo ti ma n bu ẹnu atẹ lu isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun