Kylie Jenner ń pa $360m lọ́dún kan, tó sì ta adarí Facebook yọ

KYLIE JENNER Image copyright Getty Images

Atẹjade kan ti ajọ Forbes Billionaires fi lede wi pe, Kylie Jenner ni ọdọmọde olowo julọ ni agbaye.

Kylie Jenner to jẹ abikẹyin ninu idile wọn, di ọlọla ni pasẹ ohun elo amaradan ati asaraloge ti oun ta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSeyi Makinde: Màá fẹ́ káwọn aráàlú mọ ìpa ìjọba mi lára sí rere

Ọmọ ọdun mọkanlelogun naa, to da ile isẹ rẹ Kylie Cosmetics silẹ ni bi ọdun mẹta sẹhin, ti ni ere to to miliọnu lọna ọtalelọọdunrun dọla ni ọdun to kọja.

Image copyright Getty Images

Arabinrin naa tun ta Mark Zuckerberg yọ, ẹni to da oju opo ikansiraẹni Facebook silẹ, ti wọn si ri bii ọdọmọde olowo to ni ọpọ biliọnu dọla lẹni ọdun mẹtalelogun.

Amọ Mark Zuckerberg ti ja wa sẹyin ninu awọn ọlọla agbaye ni ọdun to kọja, ti oludasilẹ ile isẹ Amazon, Jeff Bezos, si di ọkunrin to lowo julọ lagbaye.

Amọ ninu gbogbo awọn ọlọla ti iwe atẹjade Forbes Billionaire gbe jade, awọn obinrin mejilelaadọrin lo ti di ọlọla ni pase isẹ ọwọ wọn, eleyii ti ko waye lati bi ọdun mẹrindinlọgọta sẹhin.

Orilẹede Amẹrika lo ni awọn ọlọla to pọju lọ pẹlu awọn olowo toto ẹgbẹta le meje (607), nigba ti orilẹede China tele won pelu olola to to okoolelọọdurun ati mẹrin (324), nigba ti Ilẹ Gẹẹsi si ni ọlọla mejilelaadọrun.