Buhari: Obasanjo ló mú ìgbéga bá òṣèlú Nàìjíríà, ó yẹ ká yìn-ín

Obasanjo ati Buhari Image copyright Obasanjo Official
Àkọlé àwòrán Muhammadu Buhari: Obasanjo ló mú ìdàgbàsókè bá ìjọba àwa-àra-wa Nàìjíríà

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ṣe àfiwé ààrẹ àná, Olusegun Obasanjo gẹ́gẹ́ bíi olùfarajì tòótọ fún ìdàgbàsóke Nàìjíríà tó sì yẹ láti máà gbóríyìn fún.

Buhari ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ribiribi ti Ọbasanjọ ti gbése lo mu ki ìjọba awa ara wa àti ìsọ̀kàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ó gbòòrò si.

Nínú àtẹjáde kan ti Garba Sheu, to jẹ oluranlọwọ pataki fún ààrẹ kọ láti fi ki ààrẹ ànà Olusegun Obasanjo fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kẹrìnlélọgọrin rẹ, ni Buhari ti woye ọrọ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Ààrẹ Buhari ni "bó tilẹ jẹ pé èmi àti Obasanjo ò jọ dúró si ibi kan náà lórí ọ̀rọ̀ ètò òṣèlú, síbẹ̀ mi ò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ múu nítori gbogbo àwọn iranwọ rẹ̀ lórí ìdàgbàsókè Nàìjíríà."O ní, "àwọn àlàyé ti Oloye Olusegun ṣe nipa ara rẹ̀ àti àwọn amuyẹ adarí to ni, máà ń fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni ìwúrí. "

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSeyi Makinde: Màá fẹ́ káwọn aráàlú mọ ìpa ìjọba mi lára sí rere

Gẹ́gẹ́ bi Buhari ṣe sọ, "ọ̀nà ti Nàìjíríà gba láti kúrò nínú ìjọba ológun sí ti alágbáda lọdún 1979, kò ṣẹ̀yìn àwọn iṣẹ́ribiribi ti Obasanjo gbé se fun ìdagbasoke àpapọ orilẹ̀-èdè Nàijiríà".

Ààrẹ Buhari ni, "Bí ó ṣe wá ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbì ọdún méjìlélọ́gọ́rin, mo gbàdura fún àlékun àláfíà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ nínú sínsin Ọlọrun àti ènìyàn"