Nigeria Election 2019: Ará Eko pariwo ohun márùn-ún tí wọn ń fẹ́ lọ́wọ́ ìjọba tó ń bọ̀

Nigeria Election 2019: Ará Eko pariwo ohun márùn-ún tí wọn ń fẹ́ lọ́wọ́ ìjọba tó ń bọ̀

Nibayii ti eto idibo gomina ku fẹẹrẹfẹ, BBC Yoruba lọ sigboro lati mọ ohun marun ti awọn olugbe ipinlẹ Eko n foju sọna fun, lọdọ gomina tuntun to ba gba ijọba nipinlẹ Eko.

Lara awọn ohun tawọn eeyan si n pariwo pe awọn n poungbẹ rẹ, ni eto irinna.

Wọn n fẹ ki ijọba mu agbega ba eto iriina ọkọ ero ati ti BRT to jẹ ti mẹkunnnu, pẹlu atunse awọn opopona kan to ti dẹnu kọlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni wọn n fẹ ki ipese ina ọ̀ba to duro re wa, isẹ oojọ fun awọn ọdọ to sẹsẹ jade kuro nile ẹkọ giga, ipese oogun sawọn ibudo ilera ati itọju awọn alaisan bo ti yẹ.

Awọn olugbe ipinlẹ Eko tun ni awọn n fẹ kijọba pe awọn agbalẹ oju popo pada, kijọba tuntun si tun mu agbega ba eto ẹkọ, ti awọn akẹkọ nipinlẹ Eko ko fi ni maa fidi rẹmi mọ, ninu idanwo asejade kuro nile ẹkọ girama agba, WAEC.

Ẹ gbọ awọn ohun miran tawọn eeyan ipinlẹ Eko n foju sọna fun lọdọ gomina tuntun ti wọn ba dibo yan, ninu fidio yii.