Kwara governorship: Gómìnà tí wọ́n yàn ní Kwara, Abdulrazaq ní òun yóò tún ìdigunjalè Offa yẹ̀wò

Abdulrazaq Abdulrahaman Image copyright Rasaq Abdulrahaman
Àkọlé àwòrán Ó ní òun yóò foríkorí pẹ̀lú agbófinró láti ṣàwárí àwọn tó wà ní ìdí ìdigunjalè náà

Gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni Kwara, Abdulrahaman Abdulrazaq ti ṣeleri ati fikunlukun pẹlu awọn ọlọpaa lati rii pe gbogbo awọn ti wọn lẹbọ lẹru lori idigunjale to waye ni ilu Ọffa jẹjọ bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.

O ni oun yoo ri daju pe gbogbo ilana ofin to yẹ ni wọn tẹle ki gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ si lee jẹjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#Governorship Election: Òjò ni wá, a kò bẹ́nì kan ṣọ̀tá -Sanwo Olu

Lasiko to fi n sọ ọrọ idupẹ rẹ lẹyin ti ajọ INEC kede rẹ gẹgẹ bii olubori idibo gomina to waye ni ipinlẹ Kwara lo sọ eyi di mimọ.

O ni oun ti o han si oun ati ọpọ ọmọ ipinlẹ naa ni pe awọn oniṣẹ ibi ti gbajọba ni ipinlẹ naa de ibi pe awọn olugbe ibẹ ko lee di oju sun mọ.

O ni ọpọ awọn banki ni ẹkun idibo guusu ipinlẹ Kwara ni wọn ko ṣi banki wọn mọ lẹyin idigunjale to waye ni ilu Offa naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAPC jáwé olúborí nípínlẹ̀ Ekiti

"Eyi si n ṣe ọpọ akoba fun idagbasoke eto ọrọ aje ni ẹkun naa. A o forikori pẹlu awọn ọlọpaa lati mojuto ipenija eto abo .

"Eeyan mẹtalelọgbọn lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ idigunjale ilu Offa, gẹgẹ bii awọn ọlọpaa si ti ṣe sọ, awọn oṣiṣẹ ijọba kan lọwọ ninu rẹ."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGovernorship Election Results: Seyi Makinde sọ ọ̀rọ̀ àkọ́sọ lẹ́yin èsì ìbò