Emeka Ihedioha: Ibo 273,404 lo ni, ti Nwosu to tẹle si ni ibo 190,364.

Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni Imo, Emeka Ihedioha Image copyright Emeka Ihedioha/Twitter
Àkọlé àwòrán Igbakeji Abẹnugan Ile Igbimọ Aṣoju-ṣofin nigba kan ri, Emeka Ihedioha lo jawe olu bori

Ajọ eleto idibo INEC ti kede Igbakeji olori Ile Igbimọ Aṣoju-ṣofin nigba kan ri, Emeka Ihedioha to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP gẹ́gẹ́ bii ẹni to jawe olubori ninu idibo gomina Ipinlẹ Imo.

Ẹni to gbe ipo keji ni Uche Nwosu ti ẹgbẹ oṣelu AA, iyẹn àna gomina ipinlẹ naa Rochas Okorocha. Ibo naa fa awuyewuye to pọ ti awọn eniyan si bẹnu atẹ lu bi Okorocha ṣe fa àna rẹ kalẹ lati rọpo rẹ.

Ihedioha ni ibo 273,404 ti Nwosu si ni ibo 190,364.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Oludije ẹgbẹ oṣelu APGA, Ifeanyi Ararume ṣe ipo kẹta pẹlu ibo 114, 676 ti Hope Uzondima ti ẹgbẹ oṣelu APC si ṣe ipo kẹrin, pẹlu ibo 96,458.

Gomina Imo tẹlẹ ri, Ikedi Ohakim lo gbe ipo karun-un pẹlu ibo 6,846.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGovernorship Election Updates: Sanwo-Olu se abẹwo idupẹ si Bọla Tinubu

Ki wọn to ṣe ikede naa, rogbodiyan fẹ bẹ silẹ ni ipinlẹ naa, bi awọn ọmọ ẹgbẹ AA ati PDP ṣe n leri wipe, awọn yoo da wahala silẹ ti oludije awọn ko ba bori.

Nitori naa ni INEC ṣe kọkọ da ikede naa duro.