Obasanjọ pàrọọwà sí Makinde: yàgò fún òṣèlú sọ ọ́ sápò

Aworan Makinde ati Obasanjo Image copyright Kehinde Akinyemi
Àkọlé àwòrán Makinde ni o jaweolubori idibo Gomina Ipin Oyo to waye laipe yi

Aarẹ ana lorileede Naijiria oloye Olusegun Obasanjo ti parọwa si Seyi Makinde pe ki o yago fun oṣelu sọ sapo.

Arọwa yi waye nigba ti Makinde ati awọn ikọ rẹ ṣabẹwo si Obasanjo nilu Abeokuta.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ Kehinde Akinyemi fi sita Obasanjo gba Makinde lamọran pe ko''ma ṣe ba wọn kopa ninu oṣelu ti yoo ṣanfaaani fun awọn apa kaan''

Image copyright @seyiamakinde
Àkọlé àwòrán Makinde tun ṣe abẹwo si alagba Fasoranti nilu Ondo

Aarẹ ana ohun sọ pe Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan naa ni iṣe lati ṣe nipa mimu idagbasoke ba ipinlẹ Oyo to si tun kesi awọn eeyan ipinlẹ naa lati gbaruku ti.

''Jẹ alakoyawọ ki o si dawọ le awọn akanṣe iṣẹ eleyti ti yoo mu inu ara ilu dun''

Image copyright @seyiamakinde
Àkọlé àwòrán Makinde ati Falae

O sọfun pe o gbọdọ fun ara ilu ni nnkan to da yatọ si ''eleyi ti aburo mi a ma pe ni oṣelu sọ sapo.''

''Jẹki wọn ma bere wi pe nibo ni iru ijọba yi wa lati ọjọ yi.''

Obasanjo se'leri lati gbaruku ti ijọba tuntun naa ati wi pe nigbakigba ti wọn ba nilo amọran ohun,oun yoo duro gẹgẹ bi baba fun wọn.

Ninu ọrọ ti rẹ, Makinde ni abẹwo naa wa lati dupẹ lọdọ Obasanjo ki ohun si beere amọran lọdọ agba oṣelu naa.

Yatọ si aarẹ Obasanjo, Makinde tun ṣe abẹwo si alagba Fasoranti ati alagba Olu Falae nipinlẹ Ondo.