Lagos building collapse: Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó bẹ̀rẹ̀ ilé wíwó ní Lagos Island

Iroyin to n tẹwa lọwọ ni pe ijọba ipinlẹ Eko ti bẹrẹ si ni wo awọn ile ti ko duro daada ladugbo ibi ti ile ti wo pa eeyan to to mejidinlogun.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ, ile mọkandinlogun ni yoo fara gba ninu igbesẹ yi lara awọn ile ogoje ti wọn ti fagile pe awọn yoo wo.

A gbo bakanna pe wọn ti bẹrẹ si ni wo awọn ile ni Adugbo Freeman nilu Eko.

Akọrọyin wa to kalẹ sibi ti wọn ti n wo awọn ile naa ti n fi awọn aworan ile ti wọn yoo wo ranṣẹ si wa

Àkọlé àwòrán Aworan ọkọ katapila nibi ti ile ti wo nilu Eko
Àkọlé àwòrán Ile ti ijọba fẹ wo ni Lagos Island

Lara ohun ti awọn eeyan ke ni gbajare lasiko ti wọn doola ẹmi awọn ti ile wo pa ni Ita faji lọjọru ni pe ki ijọba wa wọrọkọ fi ṣada lori awọn ile to fẹ wo tan ti awọn eeyan wa ninu wọn.

Àkọlé àwòrán Ile wiwo bẹrẹ l'Eko

Ninu fọnran fidio yi ti a ti ba awọn eeyan sọrọ wọn bẹnu atẹ lu bi awọn oṣiṣẹ eleto ile kikọ kan ti ṣe n gba abẹtẹlẹ lọwọ awọn ti wọn ba ti fagile ile wọn fun wiwo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLagos building collapse: Àwọn òbí ń kérora lórí ikú àwọn ọmọ wọn nínú ìjàmbá ilé tó wó

Related Topics