Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó kéde ìyè èèyàn tókú ní ilé alájà tó wó l'Eko

Aworan awọn ti wọn gba itọju
Àkọlé àwòrán Aworan awọn ti wọn gba itọju

Lẹyin ọjọ meji ti ile wo pa awọn eeyan nilu Eko,ijọba ipinlẹ Eko ti kede iye eeyan ti o ku ninu iṣẹlẹ ohun.

Ninu atẹjade kan ti oludari eto iroyin ni ile iṣẹ eto ilera Adeola Salako fi sita,lorukọ Komisana fun eto ilera, Jide Idris, o sọ pe oku eeyan ogun ni wọn gbe lo si awọn ile igbokupamọ nipinlẹ Eko.

O salaye pe awọn to farapa marundinlaadọta ni wọn gbe lọ si awọn ile iwosan kaakiri Eko.

Image copyright Facebook/Lagos State Ministry of Health
Àkọlé àwòrán Jide Idris ni awọn dupẹ lọwọ gbogbo eeyan to kopa ninu idoola ẹmi awọn eeyan

Ikede iye eeyan to ku yi jẹ ohun ti awọn ara ilu ti n reti lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye ti awọn kan si n ro wi pe iye eeyan ti ijọba kede kere si iye ti o ku.

Ni idahun si ọrọ to n ja rainrain nipa pe awọn kan n gba owo itọju lọdọ awọn to farapa,Idris ni awọn ti fọwọ r ahesọ yi sẹgbẹ kan nitori pe Gomina Ambode tio psaẹ ki wọn ma ṣe gba owo lọwọ ẹnikẹni to ba farapa.

''Gbigba owo lọwọ awọn to farapa kii ṣe nnkan to buru nikan bii kii ṣe iwa ọdaran''

O kesi gbogbo awọn mọlẹbi ẹni to ba fara pa kankan ti awọn oṣiṣẹ ilera ba fẹ gba owo lọwọ wọn lati mu eriwa fun awọn.

Àkọlé àwòrán Awọn oṣiṣẹ pajawiri gbiyanju pupọ lati doola ẹmi awọn ti ile naa wo lu

Ogbẹni Idris dupe fun awọn ọlọdani ati ara ilu fun iranlọwọ ti wn ṣe fun awn to farapa.

O wa tẹsiwaju pe lowurọ ọjọ ẹti,eeyan mẹrinla,agbalagba mẹewa ati ọmọde mẹrin, ṣi n gba itọju fun oniruuru ipenija ilera ti awọn si ni ireti pe nigba ti ile o ba fi ṣu awọn dokita yoo da wọn silẹ lati lba mọlẹbi wọn.