Building Collapse: Ìdí tí ilé fi ń wó nìyí'

Ita Faji Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ile wo pa ọpọ eeyan l'Eko

Lẹyin ti ile alaja mẹta da wo ni Ita-Faji lagbegbe Lagos Island niluu Eko, ile iṣẹ iroyin BBC ṣe iwadii ohun to le maa ṣokunfa ile wiwo.

Bakan naa tun ni a ṣagbeyẹwo ohun ti o n fa ti iru iṣẹlẹ bayii ṣe wọ pọ nilẹ Afirika.

Bi iwadii ti n lọ lọwọ lori ohun fa sababi ile to wo l'Eko, awọn onimọ ẹrọ ti sọ fun wa awọn nnkan ti o maa n fa irufẹ iṣẹlẹ yii gan an.

1. Ipilẹ ti ko lagbara

Owo gọbọi ni ipilẹ ile to dantọ maa n jẹ, onimọ nipa ile kikọ kan, Ọjọgbọn Anthony Ede ti fasiti Covenant niluu Ota, ipinlẹ Ogun sọ pe ipilẹ ile to lagbara le gba idaji owo ti eeyan maa na sori gbogbo ile.

O ni ohun meji to ṣe pataki lori ṣiṣe ipilẹ ile ni bi ilẹ ba ṣe lagbara to ati bi ile naa maa ṣe tobi to.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ile wiwo ni Afirika

2. Awọn ohun elo ikọle ti ko lagbara

Lọpọ igba awọn ohun elo ikọle ti awọn oṣiṣẹ mọlemọle maa n lo kii saba lagbara to.

Onimọ nipa ile kikọ Hermogene Nsengimana lo sọ bẹ, o ni awọn ibikan wa to jẹ pe awọn ohun elo ikọle ti ko lagbara nikan ni wọn maa n ta nibẹ.

Ọgbẹni Nsengimana tiẹ tun sọ pe ọpọ awọn agbaṣẹṣẹ maa n mọnmọn lo ohun elo ti ko lagbara nitori ki wọn le ri owo to pọ.

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Ile wiwo ni Kenya

3. Awọn oṣiṣẹ maa n ṣe aṣiṣe

Nigba miran ti oniṣẹ ba tiẹ ra ohun elo ikọle to jẹ ojulowo, awọn oṣiṣẹ le maa po gbogbo rẹ pọ daradara.

Eyi ni ọkan lara awọn idi onimọ ẹrọ nipa ikọle Henry Mwanaki Alinaitwe ati Stephen Ekolu sọ pe o jẹ kile to wo ni orilẹede Uganda lọdun 2004 wo.

4. Ti ẹru ile ba wuwo ju bo tiyẹ lọ

Awọn onimọ ẹrọ nipa ile kikọ sọ pe kosi bi ile ko ṣe ni wo lulẹ nigba ti ẹru to wa lori ipilẹ ba ti wuwo ju.

5. Ọpọ lo n gbenu ile ti ijọba ti ṣami wiwo si

Lọpọ igba ni ijọba ti ṣami si awọn ile kan lati wo ṣugbọn ti wọn ko tii wo.

Iru eyi gan an lo ṣẹlẹ l'Ọjọru ni Ita-Faji lagbegbe Lagos Island niluu Eko