Building Collapse: Àwọn èèyàn mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ló n ṣiṣẹ́ níbẹ kí ilé náà tó wó

Aworan ile to wo ni Ibadan
Àkọlé àwòrán Awọn ara adugbo ni ṣadede ni ile na wo mọ awọn to n ṣiṣẹ nibe lori

Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri lorileede Naijiria NEMA ni ko si ẹnikankan to ku ninu iṣẹlẹ ile to wo nilu Ibadan lọjọ ẹti.

Iṣẹlẹ yi waye ni ọjọ meji lẹyin ti ile kan dawo lEko l'Ọjọru nibi ti ogun eeyan ti padanu ẹmi wọn.

Ọga ajọ naa ni iwo oorun Guusu to n mojuto awọn ilẹ kaarọ ojiire eleyi ti Ibadan wa labẹ wọn Slakku Luggard lo sọrọ yi fun BBC.

O ni eeyan meje lawọn doola labẹ ile na ṣugbọn ko si ẹnikẹni to padanu ẹmi nibẹ.

Saaju, Ikọ BBC Yoruba kan si agbegbe ibi ti ile alaja mẹta naa ti da wo nilu Ibadan.

Gẹgẹ bi ohun ti akọroyin wa jabọ ati ohun ti awọn ara adugbo sọ, eeyan mẹrindinlogun lo n ṣiṣẹ nibẹ nigba ti ile naa dawo.

Ọga ọlọpaa nipinlẹ Ibadan Shina Olukọla na fi to awọn oniroyin leti pe awọn doola ẹmi eeyan mẹta nibẹ.

Àkọlé àwòrán Ile miran tun wo ni Ibadan

Ni agbegbe Ṣogoye lẹgbẹ Molete ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Kete ti o ṣelẹ lawọn kan ti ọrọ naa soju wọn ti fi ọrọ sita loju opo Twitter

O sọ ninu ọrọ rẹ pe o ṣeeṣe ki awọn si wa labẹ awoku ile naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸgbọ́n olóògbé Suga: Wọ́n yìnbọn fún Suga lójú mi, n kò sì lè dá wọn dúró

@TopsyAshaolu ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ ni awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ko tete debi ti ile naa ti da wo lulẹ.

Ẹnikan to n gbe agbegbe ti ile naa ti wo ṣalaye pe wọn si n kọ ile naa lọwọ ni