"Bí nnkan kàn bá ṣẹlẹ̀ sí ilé mí má pé ìjọba lẹjọ"'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àwọn aladugbo ibí tí ìjọba Èkó tí n wó ilé sọ èrò ọkàn wọn

Awifuni ki o to dani agba ijakadi ni Yoruba a ma wi.

Ọrọ olugbe adugbo Lagos Island kan fẹ jọ mọ owe yi pẹlu bi o ti ṣe fi ikilọ sita fun ijọba ipinlẹ Eko pe ki nnkankan ma ṣe ile rẹ lasiko ti wọn n wo awọn ile lagbegbe naa nilu Eko.

Baba Alatiṣe n gbe ni opopona Smith ni Isale Eko ti o si ba ikọ BBC sọrọ nipa igbesẹ ijọba lati wo awọn ile kọọkan ti ko duro re e.

''Ijaiya lo jẹ fun mi bi mo ti ṣe ri awọn to fẹ wo ile pẹlu pe kii ṣe ile mi ni wọn fẹ wo.''

Baba Alatishe ni wọn ko j ki ohun pari ounje ti ohun njẹ ki wọn to le ohun jade kuro ninu ile

''Wọn ko sọ fun wa wi pe wọn fẹ́ wo ile,bi bẹẹ kọ , a ko ba ti palẹmọ ara wa ki wọn to de.Mo sare gijogijo sọkalẹ ni lati le fi daabo bo ẹmi mi.''

Ka ni wọn fun mi ni ọgbọn iṣẹju lati palẹmọ ara mi nitori pe mo n jeun lọwọ, kii ba da.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa fi ikilọ sita pe ti nnkankan ba ṣẹlẹ si ile ohun,ile ẹjọ ni yoo pari ọrọ laarin ohun ati ijọba.

Lọjọ ẹti ni ijọba bẹrẹ si ni wo awọn ile ti ko duro daada ladugbo Lagos Island.

Igbesẹ yi waye lẹyin igba ti ile wo pa awọn eeyan ogun lọjọ iṣẹgun ladugbo ọhun.