Offa Bank Robbery: Àwọn afunrasi ní àwọn kò fí t'inu fẹdo jẹwo fún ọlọ́pàá

Ọwọ ti tẹ

awọn afurasi yooku ti ọlọpaa gbe jade ree Image copyright NIGERIA POLICE
Àkọlé àwòrán Ọjo Kerin Oṣun Kẹrin ọdun 2018 lawọn afunrasi naa yabo ile ifowopamọ nilu Offa ti wọn si pa eeyan mẹtalelọgbọn

Mẹta ninu awọn afunrasi to n jẹjọ lori ẹsun ipaniyan ati idigunjale to waye nilu Offa lọdun to kọja ti sọ fun ile ẹjọ pe iya lawọn ọlọpaa fi gba ọrọ ijẹwọ lẹnu awọn.

Agbẹjọro awọn olujẹjọ naa Mathias Emeribe lo pe igbẹjọ laarin igbẹjọ to n waye lọwọlọwọ lati fi salaye bi awọn to n soju ko ti ṣe finu fẹdọ jẹwọ fun awọn ọlọpaa.

Labẹ ofin,ile ẹjọ ko le gba ọrọ ti afunrasi ba fi ipa sọ fun ọlọpaa wole.

Gẹgẹ bi ohun ti awọn afunrasi mẹta naa Ayoade Akinnibosun,Ibikunle Ogunleye ati Adeola Abraham sọ, niṣe ni awọn ọlọpaa de awọn ni ọwọ mejeeji pẹlu irin ti wọn si fi iya jẹ awọn lati s ohun ti wọn fẹ.

Wọn tun fí ẹsun kan awọn ọlọ́pàá pe wọn yin awọn ni ibọn lẹsẹ.

Awọn olujẹjọ naa ni awọn ọlọpaa SARS ni wọn gbe awọn lati ofisi wọn to wa nilu Ilorin lo si ile iṣẹ ọtẹlẹmuye Intelligent Response Team to wa labẹ akoso ọga ọlọpaa, Abba Kyari.

Bakanna ni awọn afunrasi naa fi ẹsun kan awọn ọlọpaa pe wọn pa awọn Fulani maarun ati ọlọpaa tẹlẹri kan Micheal Adikwu ti o jẹ olori awọn adigunjale Offa naa.

Àkọlé àwòrán Awọn agbẹjoro mejeeji to n soju ijọba ati awọn afunrasi naa wi tẹnu wọn ni iwaju adajọ

Agbẹjọro ìjọba, Bola Gold naa fí ọrọ wa awọn afunrasi naa lẹnu wo.

Adájọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà, Halima Salman mú Ìgbẹ́jọ́ náà wá sí òpin lẹ́yìn wákàtí méje tí ilé ẹjọ́ náà fí ọ̀rọ̀ wá afurasí náà lẹ́nu wò.

Adájọ́ Salman sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹẹdọgbọn osùn kẹrin ọdún fún tí tẹ sìwájú ẹjọ́ náà.

Lana ọ̀jọ́bọ ni Olujẹri (Police witness), Hassan Attila ṣe àlàyé fún ilé ẹjọ́ bí ọwọ sikun àwọn ọlọ́pàá tí ṣe tẹ àwọn afurasí náà tí wọ́n sì gbé wọn lọ olú ilé ìṣe àjọ ọlọ́pàá ní ìlú Abuja nínú osun karùn-ún ọdún 2018.

Àwọn afurasí márùn-ún tó ń jẹjọ fún ẹsun idigunjale ati ipaniyan naa yabo awọn ile ifowopamọsi nìlú Ọ̀ffà nibi ti wn ti pe eeyan ọgbọn lOsu kẹrin ọdún tó kọjá .