Rivers Governorship Election: Àwọn janduku àti ọmọ ilé ìṣẹ́ ológun ló wà nìdí ìdìbò tó dàrú

Awọn ara ilu n kawo soke loju titi ni
Àkọlé àwòrán Wahala to tẹyin idibo naa pọ debi wi pe awọn eeyan koribijade lo si ibi'ṣẹ

Ajọ eleto idibo orileede Naijiria ti gbe esi iwadi ti wọnṣe jade lori ohun ti o fa wọduwọdu lasiko idibo Gomina nipinlẹ Rivers.

Ninu abajade iwadi igbimọ ti wọn ṣe agbekalẹ rẹ sọ, awọn ọmọ ileeṣẹ ologun kan ati awọn janduku to yabo ibudo ti wọn ti n ko esi ibo jọ ni o da eto idibo naa ru.

Wahala to bẹ silẹ lasiko idibo Gomina naa ni o mu ki Inec so idibo si ipo Gomina ati ti ile aṣofin rọ lọjọ kẹwa Oṣu kẹta ọdun 2019 .

Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán Atẹjade Inec

Amọ ṣa ajọ naa ni awọn yoo ṣi yi ba awọn oṣiṣẹ alabo ilu gbogbo jiroro lori bi awọn eeyan wọn ko ṣe ni ma ṣegbe lasiko idibo.

Gẹgẹ bi ohun ti a ri ka ninu atẹjade kan tioludari eto ifọrọto ara ilu leti ati idanilẹkọ awọn oludibo Festus Okoye buwọlu,Inec ni awọn fi idi ọrọ mulẹ pe idibo waye ni pupọ ninu awọn agọ idibo ti awọn si kede esi wọn.

Ninu ẹka asoju mejilelọgbọn Inec ni awọn kede esi dibo to waye ni aaye idibo mọkanlelogun.

Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán Atẹjade Inec

Ajọ Inec ni awọn ko ni ko irẹwẹsi ọkan lati pari eto idibo nibi ti awọn ti kede esi ibo.

Okoye wa salaye pe awọn yoo pawọpọ pẹlu gbogbo awọn ajọ to ba yẹlati ri wi pe eto idibo nipinlẹ naa ni iyanju.

O so pe Ogunjọ osu kẹta ni wọn yoo sọ igba ti idibo naa yoo pada waye ati gbogbo ilana ti awọn yoo fi ṣeto naa.