Gbenga Daniel: Ìdí tí mo fi kọ̀wé fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP silẹ

Atiku, Peter Obi ati Gbenga Daniel Image copyright @Demolalanrewaju

Gbajugbaja oloṣelu to fi igba kan jẹ Gomina ipinl Ogun Gbenga Daniel ti kowe fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ.

Saaju asiko yi, Daniel ni oludari ipolongo ipo aarẹ fun Atiku Abubakar to jẹ oludije gbẹ oṣelu PDP ninu idibo aarẹ to kọja.

Ikede ifiposilẹ rẹ wa ninu atẹjade kan ti o fi sọwọ si alaga ẹgbẹ oṣelu PDP,Uche Secondus.

Ninu atẹjade naa,Daniel ni oun dupe pupọ lọwọ ẹgbẹ ati awọn ọrẹ ṣugbọn oun to ku bayi ni pe oun fẹ gbajumọ ọrọ mi to yatọ si oṣelu.

Ni pato,o ni ohun ṣetan lati ṣe ajinde ẹgbẹ ohun ti ko ni owo ijọba ninu ti orukọ rẹ n jẹ Gateway Front Foundation.

Image copyright Facebook/Gbenga Daniel
Àkọlé àwòrán Gbenga Daniel fi PDP silẹ

Gbenga Daniel ni ṣe ni laanu bi ẹgbẹ PDP ti ṣe n koju ipenija to niṣe pẹlu yiyan oludije saaju idibo to waye ni ọjọ Kẹsan Osu Keta eleyi to mu ki ede aiyede wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ.

O lohun dupe pe ohun ti ara ilu fẹ lo pada ṣe nipa Gomina ati awọn asoju ipinlẹ Ogun ti o si ni inu ohun dun pe awọn ti mu opin ba ijba ti o n tako ifẹ ara ilu.

Gbenga Daniel ti jẹ Gomina ipinlẹ Ogun fun ọdun mẹjọ.