Bàbá tó pokùnso: Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni ọmọdébìnrin tí baba rẹ̀ bá seré oge

Okun ti wọn ta lati pokunso Image copyright Times

Ọkunrin kan, Razak Hamed ti pokunso ni ahamọ awọn osisẹ aabo ara ẹni, laabo ilu, NSCDC, nilu Akurẹ.

Ṣe bi ko ba nidi, obinrin kii jẹ Kumolu, ẹṣun to gbe ọkunrin naa de ahamọ ni pe, o ba ọmọdebinrin rẹ, ọmọ ọdun mẹjọ ni ajọsepọ.

Nigba to n salaye fun akọroyin BBC Yoruba lori bi isẹlẹ naa se waye, agbẹnusọ fun ileesẹ Civil Defence nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Samuel Ọladapọ sọ pe Ibrahim Ahmed, tii se ọmọkunrin oloogbe naa lo wa si ọọfisi awọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọladapọ ni Ibrahim Hamed lo wa fi ẹjọ baba rẹ sun pe o ba aburo oun, Zenab, ọmọ ọdun mẹjọ lo pọ, eyi to mu ki ẹru maa ba oun.

O ni idi ree ti awọn osisẹ awọn fi tẹle lọ sile, tawọn si mu baba rẹ wa si olu ileesẹ NSCDC ni ọjọ Aje, lati gba ọrọ ẹnu rẹ silẹ.

Alaye Ọladapọ ree siwaju si:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSokoto ni baba to ba ọmọ rẹ lo lati pokunso

Agbẹnusọ fun ajọ NSCDC fikun pe, nigba ti afurasi naa, Razak n sọ tẹnu rẹ, o ni lootọ ni oun n ba Zenab ni ajọsepọ, iṣẹ esu si ni isẹlẹ naa.

"Nigba ta beere lọwọ rẹ pe iyawo rẹ n kọ, ọkunrin naa ni iyawo oun akọkọ to bi Ibrahim fun oun, ti ṣe alaisi nigba ti iyawo keji to bi Zenab ti kọ oun silẹ.

A gba afurasi naa laaye lati pe awọn mọlẹbi rẹ, ki wọn lee wa gba oniduro rẹ, nitori ẹsẹ to ṣẹ́, ṣe e gba oniduro rẹ."

Ọladapọ ṣalaye siwaju pe awọn ẹbi afurasi naa wa, ti wọn si n ṣẹ epe fun pe o ti jẹ eewọ. A rọ wọn lati wa fi ọwọ si iwe lati gba oniduro rẹ sugbọn wọn ko pada wa, boya nitori pe ohun to se ko dun mọ wọn ninu rara ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCollapsed Building: Ayálégbé ló dára bí ìjọba ṣe wólé àmọ́ wọ́n fẹ́ ìrànwọ́ ilé míràn

O ni bakan naa lawọn ni ki wọn lọ gbe ounjẹ́ wa fun. Irọlẹ ọjọ yii naa lo ni ọkunrin naa ni otutu n mu oun, tawọn si ni ko bọ asọ, ti wọn si mu sinu ahamọ ninu yara kan, oun nikan si lo wa ninu yara naa.

Ọladapọ ṣalaye pe nigba to ya, ẹnikan ninu ẹbi rẹ gbe ounjẹ rẹ wa, tawọn si ni ki wọn lọ mu wa, ko lee jẹnu.

"Igba ta de inu yara naa, lawọn osisẹ civil defence ri pe o ti fa sokoto rẹ ya, o so mọ irin kan, to si ti pokunso ninu yara to wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Isẹlẹ yii soju ẹbi rẹ to gbe ounjẹ wa, ta si kesi awọn ọlọpa lati wa dasi isẹlẹ yii."

Ni bayii, wọn ti gbe oku Razak lọ sile iwosan lati mọ ohun to paa, ti iwadi si n tẹ siwaju.