HIV/AIDS: Ìjọba Nàìjíríà gbé èsì ìwadìí tuntun jáde lóríi ọwọ́jà HIV/AIDS

Wọn n ṣe ayẹwo ẹjẹ eeyan kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iye awọn to ni kokoro arun naa ti dinku lorilẹede Naijiria, gẹgẹ bii iwadii ajọ NACA naa ṣe sọ

Eeyan to din diẹ ni miliọnu meji lo ni kokoro arun HIV/AIDS lorilẹede Naijiria, ṣugbọn njẹ o mọ pe obinrin lo pọ ju laaarin wọn?

Eyi ni ọkan lara awọn koko to jẹyọ ninu iwadii ijinlẹ kan, ti ajọ to n gbogun ti itankalẹ kokoro arun HIV/AIDS lorilẹede Naijiria, NACA, ṣẹṣẹ gbe jade.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tẹlẹ ri, ohun ti iwadii n sọ ni pe, eeyan to le diẹ ni miliọnu mẹta lo ni kokoro arun naa,.

Ṣugbọn gẹgẹ bii oludari agba fajọ NACA, Dokita Sani Aliyu, to gbe abajade iwadii naa kalẹ niwaju Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe sọ, iwadii ọhun ti jẹ ki okodoro iroyin nipa kokoro arun naa lorilẹede Naijiria fi oju han bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCollapsed Building: Ayálégbé ló dára bí ìjọba ṣe wólé àmọ́ wọ́n fẹ́ ìrànwọ́ ilé míràn

Ninu iwadii tuntun yii ẹwẹ, ẹkun aringbungbun gusu orilẹede Naijiria ni ọwọja kokoro arun HIV/AIDS pọ ju si lorilẹede Naijiria, eyi si wa laaarin awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn wa laaarin ọdun mẹẹdogun si mẹrinlelọgọta pẹlu ida mẹta o le ẹyọ kan ninu ọgọrun (3.1%).

Ẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria ni ọwọja kokoro arun naa si ti lọ silẹ julọ.

Image copyright Getty Images

Dokita Aliyu ni, " Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ni eto to rinlẹ pẹlawọn alabaṣiṣẹ pọ rẹ lori igbogun ti kokoro arun HIV/AIDS lati ṣeto iranwọ ati atilẹyin fawọn to ba ti ni kokoro arun ọhun, lati pese itọju, ati lati daabo bo awọn ẹbi wọn ki wọn lee gun lẹmi, ki wọn si gbe igbe aye alaaafia.