Lagos Building collapse: Aisha Buhari ṣàbẹ̀wò ṣàwọn tí ilé wó lù níléèwòsàn

aisha Buhari n ba ọmọde kan sọrọ Image copyright Aishabuhari
Àkọlé àwòrán Ko din ni ogun eeyan to ba ijamba ile to wo ni ilu Eko naa lọ

Aya aarẹ orilẹede Naijiria, Aisha Buhari ti sọ pe igbesẹ to tọ ni ijọba ipinlẹ Eko gbe, lati dena atunṣe ijamba ile to da wo ni agbegbe Itafaji ni ipinlẹ Eko.

Aisha Buhari gbe imọran yii kalẹ lasiko to ṣabẹwo sawọn akẹkọ ileewe alakọbẹrẹ, atawọn obinrin to lugbadi ijamba ile to wo naa nileewosan.

"Ohun to bani ninu jẹ pupọ ni pe awọn akẹkọọ pupọ bayii padanu ẹmi wọn, ṣugbọn sibẹ a dupẹ lọwọ Ọlọrun, a si ki ijọba ipinlẹ Eko atawọn alaṣẹ ileewosan Lagos Island General Hospital ku iṣẹ, lori iṣẹlẹ naa."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni idunnu nla lo jẹ lati rii pe awọn ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ naa n gba itọju to pe ye, ara wọn si ti n pada bọ sipo.

Amọṣa o ni, ijọba ipinlẹ Eko gbọdọ ṣe ohun to tọ lati dena atunṣẹ iṣẹlẹ naa lọjọ iwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCollapsed Building: Ayálégbé ló dára bí ìjọba ṣe wólé àmọ́ wọ́n fẹ́ ìrànwọ́ ilé míràn

Ni ọjọ ẹti ni ijọba ipinlẹ Eko bẹrẹ si ni wo awọn ile ti o ti di ẹbiti, kaakiri awọn agbegbe kan nipinilẹ Eko nitori iṣẹlẹ to ṣẹ naa.

Dokita agba ni ileewosan naa, Dokita Gani Kalẹ ṣalaye fun aya aarẹ pe, ọmọ wẹwẹ mẹwa ni wọn ko wọ ileewosan naa lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Image copyright Bashir Ahmad

Amọṣa o fi kun un pe, mẹta ninu awọn ti wọn ko wa ni wọn ti da silẹ lẹyin ti wọn gba itọju ti ara wọn si ti da ṣaka.