New Zealand: Lateef Alabi ní òun kò lérò pé agbébọn leè kọlu mọ́ṣálásí ní New Zealand

Lateef Alabi ati awọn eeyan miran Image copyright @GbenroAdegbola

A ṣe ọmọ Naijiria ni Imaamu agba fun mọsalasi kan ti agbebọn kan kọlu ni orilẹede New Zealand lọjọ Satide.

Lateef Alabi ni orukọ rẹ, oun si lo n dele bii Imaamu ni mọsalasi naa, to si n lewaju awọn olujọsin ninu adura nigba ti ọkunrin agbebọn kan, Brenton Tarrant kọlu wọn.

Alabi ni iye eeyan ti ko ba ba isẹlẹ naa lọ ko ba pọ ju iye to ku lọ, bi kii ba se ọkunrin kan to pe orukọ rẹ ni Azeez, ẹni ọdun mejidinlaadọta, to gba gbara lọwọ agbebọn naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọ bi isẹlẹ naa se waye fun iwe iroyin London Mail, Alabi sọ pe oun sadede gbọ ariwo ni deede aago meji ku isẹju marun ni ọsan ọjọ Ẹti naa, ti oun si bojuwo oju ferese, ti oun si ri ọkunrin kan to wọ asọ agbofinro, ti oun si ro pe ọlọpa ni.

O ni oun tun ri oku eeyan meji nilẹ, ti agbegbọ̀n naa si n sọ oniruuru ọrọ ti ko wu eti gbọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCollapsed Building: Ayálégbé ló dára bí ìjọba ṣe wólé àmọ́ wọ́n fẹ́ ìrànwọ́ ilé míràn

"O wa ye mi pe apaniyan ni ọkunrin ọhun, ti mo si tete pariwo fun awọn olujọsin to to ọgọrin niye lati doju bolẹ. Wọn kọkọ lọra lati se bẹẹ, amọ bi Tarrant tun se yin ibọn miran to pa olujọsin miran, ni wọn se bẹẹ, nigba to ye wọn pe agbebọn ti de,"

Image copyright @GbenroAdegbola

Alabi sọ siwaju pe, olujọsin kan to n jẹ Aziz, nigba ti ko lee maa wo agbebọn naa niran, lo ba gba ya, to si wọya ija pẹlu rẹ, ti agbara rẹ si kaa, eyi ti ko jẹ ki agbebọn naa wọnu mọsalasi wa ba wa.

"To ba jẹ pe agbebọn naa wọnu mọsalasi ni, gbogbo wa ni ko ba ti jẹ Ọlọrun nipe, ti awọn eeyan to wa ninu mọsalasi naa si ti n lakaka lati dara pọ mọ ẹbi wọn."

Image copyright Agencies

Alabi fikun pe "Inu n bi gbogbo wa, a fẹ foju kan awọn eeyan wa to se alaisi ninu isẹlẹ naa, ka se ẹyẹ ikẹyin fun wọn, ki wọn si lọ tẹ wọn si iboji, sugbọn awọn ọlọpa fẹ pari iwadi wọn ki wọn to gbe awọn oku naa fawọn mọlẹbi wọn."

Alabi wa n beere pe ki wọn si mọsalasi ọhun pada, pẹlu ipese eto aabo to peye, o si se afikun pe, oun ko lero laelae pe irufẹ isẹlẹ bayi lee waye ni orilẹede New Zealand, nitori pe o jẹ orilẹede to ni alaafia gidigidi.