Ọọ̀ni: Àwọ̀ méje bíi pupa, aró, ewéko ni omi àjèjì náà ní

Ooni adeyeye Enitan Ogunwusi Image copyright Ooni adeyeye Enitan Ogunwusi

Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji, ti kede faraye pe oun tun ti se awari omi ajeji miran to n da nilu Ile Ifẹ.

Ọọni kede ọrọ yii lasiko to n gbalejo awọn ọmọ igbimọ alasẹ ẹgbẹ awọn eeyan to n seto irinajo afẹ ni Naijiria (NATOP), eyi ti aarẹ wọn, Bilikisu Abdul ko sodi, ni aafin rẹ.

Oriade naa ni inu ibudo igbalode nla to wa nilu Ifẹ́, Ifẹ Grand Resort, ti oun n kọ lọwọ ni wọn ti sawari omi ajeji naa, eyi ti ni awọ meje ninu eyi ti awọ buluu, eweko. pupa ati bẹẹ bẹẹ l wa.

Ọọni ni isẹ ku diẹ ko pari ni ibudo igbafẹ naa, to ba si buse tan, ẹnu yoo ya awọn ọmọ Naijiria lori awọn ohun meremere to wa nibẹ eyi ti yoo maa ta orilẹ́ede wa fawọn ilẹ okeere lagbaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Lati igba ti mo ti gori itẹ awọn baba nla mi, awọn ohun adiitu ti ko wọpọ ni mo ti se awari rẹ, eyi to kọja oye eniyan ati imọ sayẹnsi pẹlu. Awọn ohun awari ijinlẹ́ yii lo fidi rẹ́ mulẹ pe Ile Ifẹ ni orirun iran ọmọniyan lagbaye."

Ọba Ogunwusi fikun pe " Aafin yii jẹ ti atijọ, eyi to ti le ni ẹgbẹrun mẹwa ọdun, bẹẹ ni mo tun ni awọn ile to ju ọọdunrun, irinwo ati ẹẹdẹgbẹta ọdun lọ ninu aafin yii, ti wọn ti di nkan isẹmbaye to jẹ apeyawawo fun gbogbo agbaye."

Oriade naa wa rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ Naijiria lati yee na owo ribiribi lọ soke okun fun irinajo afẹ nitori ohun ti wọn n wa l si Sokoto, wa ni apo sokoto wọn nile.

Image copyright Ooni adeyeye Enitan Ogunwusi

Bakan naa ni Ọọni tun fi kun pe adanu nla to ti pọ julọ to ba Naijiria ni awari epo rọbi jẹ, nitori bi orilẹede yii se kẹyin si agbega eto irinajo afẹ patapata.

O fikun pe awọn ijọba Naijiria ti gbagbe pe orisun eto irinajo afẹ orilẹede kan ko lee gbẹ gẹgẹ bi epo rọbi to ni igba ati akoko to lee gbẹ.

Ọba Ogunwusi wa jẹjẹ atilẹyin rẹ fun ẹgbẹ awọn to n seto irinajo afẹ lorilẹede yii, to si ni awọn yoo jọ sisẹ pọ lati gbe Naijiria de oke agba.