IBDEC: Àyàfi tọ́wọ́ wa bá tẹ àwọn ọ̀dọ́ tó na òṣìṣẹ́ wa, ni iná yóò tó tàn nílẹ̀ Ìjẹ̀ṣà

Opo ina ati waya ina ọba Image copyright Jude Ugwu

Ko din ni ijọba ibilẹ mẹfa nilẹ Ijẹṣa to wa ninu okunkun biribiri bayii lati Ọjọbọ to kọja.

Ohun to sokunfa isẹlẹ naa ni bawọn ọdọ kan lagbegbe Olomilagbala ati Bọlọrunduro nijọba ibilẹ ila oorun Ilesa, se fi ẹhonu han lọ si ọọfisi ajọ amunawa to wa nilu Ilesa.

Awọn ọdọ naa ni owo ina ti awọn osisẹ IBDEC n mu wa fun awọn ti pọ ju, ti ina ọba si n se segesege lati osu mẹfa sẹyin.

Sugbọn ọrọ naa bẹyin yọ, ti awọn ọdọ yii si din dundun iya fawọn osisẹ ajọ amunawa naa ni ọọfisi wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Niwọn igba to si jẹ pe a kii mọ Alaja, ka na aja rẹ, eyi lo mu ki olu ileesẹ ajọ amunawa, IBDEC, to wa nilu Ibadan fi setan lati wa epo dẹkun fun awọn ọdọ to san iru asọ yii soro, lọna ati kọ ero ẹyin bii tiwọn lọgbọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCollapsed Building: Ayálégbé ló dára bí ìjọba ṣe wólé àmọ́ wọ́n fẹ́ ìrànwọ́ ilé míràn

Nigba to n salaye ohun ti oju awọn osisẹ ajọ amunawa ọhun ri lọwọ awọn ọdọ ọhun fawọn akọroyin, Osisẹ alarina fun ajọ IBEDC nipinlẹ Ọsun, Kikẹlọmọ Owoẹyẹ leri leka pe, inu okunkun lawọn ijọba ibilẹ naa yoo wa.

"A yọ awọn ijọba ibilẹ mẹfa to wa lẹkun Ijẹsa kuro lara agbegbe ta n pin ina ọba de, titi ti wọn yoo fi se awari awọn eeyan to kọlu awọn osisẹ wa."

Image copyright iSaac Haastrup

Sugbọn ọpọ awọn olugbe adugbo naa lo ti n fapa janu lori ipinnu ajọ amunawa yii, ti wọn si ni ipa nla ni aisi ina ọba lagbegbe awọn ti n ko ba ọrọ aje ati igbaye gbadun awọn.

Awọn ara adugbo naa ni, ki lo de to jẹ pe gbogbo awọn ni yoo jiya ẹsẹ ti awọn ọdọ kan da, wọn fikun pe, ko si ni dara ki ajọ IBDEC ba ẹnikan ja, ki wọn wa fi ọwọ gun gbogbo ile nimu.

Image copyright iSaac Haastrup

Bi o tilẹ jẹ pe wọn gba pe ohun ti awọn ọdọ naa se ko bojumu, sibẹ wọn ni ori bibẹ kọ ni oogun ori fifọ, iwa aidaa gbaa si ni ki awọn eeyan maa jiya aisi ina ọba tori ẹsẹ aimọdi.

Koda, a tiẹ gbọ pe awọn eeyan kan ti n dunkoko lati gbe ajọ IBDEC lọ sile ẹjọ lori isẹlẹ yii.