Oyo NURTW: Tokyo ló kọ́kọ́ bá Auxillary sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ọdún gbọọrọ

Tokyo ati Auxilaary plu awọn eeyan miran Image copyright Tirbune

Arẹmaja kan ko si, ajamarẹ ni ko sunwọn., ni Yoruba wi. Wọn tun ni ta ba gbagbe ọrọ ana, a ko ni rẹni ba sere.

Eyi lo mu ki awọn asaaju ẹgbẹ awakọ meji nipinlẹ Ọyọ, Alhaji Lateef Akinsọla, ti gbogbo eeyan mọ si Tokyo, ati igbakeji rẹ lasiko to fi jẹ alaga, Alhaji Lamidi Mukaila, to tun n jẹ Auxillary, fi foju rinju lẹyin ọdun mẹwa ti wọn fi n bara wọn ja.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Nigerian Tribune se gbe sita, Tokyo lo kọkọ pe Auxillary lori aago lẹyin ọdun mẹwa ti igbakeji rẹ naa, ti yẹ aga mọ nidi, ti Lateef Salakọ Eleweọmọ si di alaga.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin naa ni deede aago marun kọja isẹju meje ni irọlẹ ọjọ Aiku, ni Auxillary ati ikọ rẹ gunlẹ si ile Tokyo, ti wọn si ki wọn kaabọ tilu tifọn, ki awọn mejeeji to wọle lọ se ipade bonkẹlẹ alatilẹkun mọri se.

Amọ ki wọn to gbe ilẹkun ti, ni Auxillary ti sọ fun ọga rẹ atijọ pebaba ni baba rẹ yoo maa jẹ lọjọkọjọ, tori Tokyo si ni baba awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọk ero nipinl Ọyọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAṣọ òkè: Alákọ̀wé ní ọ̀nà láti wá oúnjẹ fáwọn tó ń ṣe aṣọ òkè ló ṣún òun débẹ̀

"Inu ile yii ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero, boya alaaye ni abi oku ti bẹrẹ, ko sẹni to lee sẹ lori eyi. Inu mi si dun pupọ nigba ti ẹ pe mi lana ọjọ Satide."

"Emi ko ni ohunkohun kankan lati fi tako yin, dipo bẹẹ, mo ri gbogbo ohun to ti sẹlẹ lati ẹyin wa gẹgẹ bii irubọ ti a gbọdọ se lati mu ki ẹgbẹ wa lọ siwaju. Abẹyin la ti bẹrẹ, mo si fẹ́ fun yin ni ọwọ rẹ."