Corruption: Ọ̀gá àgbà àṣọbodè ní kíkọ rìbá ṣàfihàn aṣọ́bodè tó ti di àtúnbí

Custom
Àkọlé àwòrán O ní onífàyàwọ́ ọ̀hún tún jẹ́ẹ̀jẹ́ pé òun yóò sàn rìbá tó tún pọ̀ jùbẹ́lọ ti tí àkọ́kọ́ yìí ba ṣe dáradára

Ilé iṣẹ́ aṣọ̀bode ti ṣe àgbéga fún ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ rẹ̀ ní Apapa, Bashir Abubakar sí ipò igbákejì ọgá agba ileeṣẹ náà.

Col. Hameed Ibrahim Ali gbé Muhammed Abba-Kura ga si ipo oludari àgbà ní agbègbè Apapa.

Abubakar kọ ààdọ́jọ mílíọ̀nù náírà, owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ti olóògùn fàyàwọ́ kan fi lọ̀ọ́, láti gbé òògùn ogoji ọkọ ajagbé tó kún fún Tramadol wọle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAṣọ òkè: Alákọ̀wé ní ọ̀nà láti wá oúnjẹ fáwọn tó ń ṣe aṣọ òkè ló ṣún òun débẹ̀

Ìròyìn fi ye ní pé, ọgá aṣọ́bodè àti àwọn ìsọ̀gbè rẹ̀ kọ owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, wọn si fi ìdí àwọn àjàgbé tó kúń fún àwọn oogun náà gúnlẹ̀, èyí tó lé ní bílíọ̀nù méje naira.

Lásìkò tó ń ba àwọn akọròyin sọ̀rọ̀ lọ̀rí ọ̀rọ̀ to ṣẹ̀lẹ̀ nínú oṣù kọkànlá òsu 2018, ọgá àgbà pátápáta fawọn aṣọbodè sọ pé " kíkọ ààdọ́jọ mílíọ̀nù náírà owó àbẹ̀tẹ̀lẹ̀, sàfihan àwọran òṣìṣẹ́ aṣọ́bode tó ti gbà àtúnṣe, ti wọn sì ń fi ọ̀rọ̀ àrá ìlú sáájú ju imọ̀ tara ẹni nikan lọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajọ asọbóde ṣe agbéga fun osiṣẹ̀ rẹ̀ tó kọ̀ rìbá

O ní onífàyàwọ́ ọ̀hún tún jẹ́ẹ̀jẹ́ pé òun yóò sàn rìbá tó tún pọ̀ jùbẹ́lọ ti tí àkọ́kọ́ yìí ba ṣe dáradára.