Ekiti: À máa fi ojú àfipa bọ̀mọdé lòpọ̀ hàn lóri tẹlẹfísọn

ỌWỌ ỌMỌDE Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ekiti: Ìjọba gb ìgbésẹ túntún láti fí ìyà jẹ ẹni tó bá bá ọmọdé lòpọ̀

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti ní àwọn yóò maa ṣe àyẹwò ọpọlọ fún gbogbo àwọn ti ilé ẹjọ bá ti dá lẹ́jọ pe ó jẹbi ẹsùn ìfipá bó ọmọde lòpọ̀.

Bákan náà ní wọn ó gbe orúkọ wọn jáde lóri ayélujara ile iṣẹ́ ìodájọ, àti pé wọn ó kéde orúkọ lóri rẹdíò àti tẹlẹfísọn, bẹ́ẹ̀ ni olóri tàbi ọba ìlú wọn yóò mọ̀ si pẹ̀lú ojú pátakó ni ilé iṣẹ́

Komisọna fún ètò ìdájọ ní ìpínlẹ̀ Ekiti ọgbẹ́nu Wale Fapohunda lọ fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ ní ìlú Ado Ekiti lọ́nìí.

Image copyright Ekiti Ministry of Justice
Àkọlé àwòrán Ekiti: À máa fi ojú àfipa bọ̀mọdé lòpọ̀ hàn lóri móhùnmáwòrán

''Àwọn ètò tí a ti ní nílẹ̀ ní pe à ó máà lẹ fótò àwọn ọdaran káàkiri ojú gbaaara ní àwọn ìlú tàbi ìletò wọn àti ìjọba ìbil.ẹ̀ ti wọn ti wá''

"À ó sàlàyé fún àwọn ọba tàbi adari ìlú wọn ẹsẹ̀ ti wọn ṣẹ, gbé àwòrán wọn sóri ẹ̀rọ alátagbà ilé ìṣẹ́ ìdájọ ti ìpínlẹ̀ Ekiti"

À ó ṣe àyẹ̀wò ọp;ọlọ tipátipá fún, pà'pàá jùlọ ẹni ti ilé ẹjọ ba ti ni ó jẹ̀bi ẹsun fífí ipí bá ọmọde sùn tó fi mọ́ ẹni tó bá ń jẹ́jọ lọ́wọ́

Ọgbẹ́ni Fapohunda ni ìdí ti àwọn fi ń gbé irú ìgbéṣẹ̀ yìí ni pé irú ìwà ìbàjk yìí ti ń pọ̀ jù, bótill jẹ pé òun mọ pé àwọn ìgbéṣẹ̀ yìí jẹ èyí to lágbára, síbẹ̀ ìgbàgbọ́ wà pé yóò ràn àwọn lọ̀wọ́, ọ̀pọ̀ ará ìlú ní yóò sì ni àǹfàní láti sọ èrò ọkàn wọn.

Àkọlé àwòrán Gbogbo ẹni tó ba ti ṣẹ si òfin ní à ó lẹ orukọ wọn àti foto

''A tí ṣe ìpìdé pẹ̀lú àwọn tọ́rọ̀ kàn ní ǹkan bii ọ̀ṣẹ̀ méjì, sùgbọ́n à ń pinu láti pé gbogbo àwọn ènìyàn láti wa sọ èrò ọkàn wọn lóri ọ̀rọ̀ àwọn tó ń ba ọmọ dé lòpọ̀ tipátipá.''

Fapohunda ni ohun ìbànújẹ ló jẹ fún òun bí ẹsùn ìbọ́mọde lòpọ̀ ṣe ń pọ̀ si lójojúmọ́ p[llú gbogbo àwọn ti ilé ẹjọ ti ń dájọ fun ní ìpínlẹ̀ Ekiti àti pé ìnú gómìnà Fayemi ń bajẹ gidigidi lóri ọ̀rs náà

O ní ìgbésẹ tuntun yìí àwọn lérò pé yóò jẹ ki àsírí àwọn ọdaràn yiìí máa tu tí yóò si fún ìjọba láǹfani láti maá yọ orúkọ àwọn irú ọdaran kúrò nínú àwọn ti wọn lé sàànú lagbà ẹwọn.