Ìlú mímọ́ nibí, wọn kò gbọdọ̀ bímọ, sin òkú àbí ẹran síbẹ̀"
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Manfe-Dove: Àgbà ìlú kan ní ohùn kan ló fọ̀ sáwọn baba ńlá àwọn láti ṣe bẹ́ẹ̀

Iwadi BBC fihan pe, eewọ ni fun alaboyun ni ilu Manfe Dove, lorilẹede Ghana lati bimọ tuntun sinu ilu naa.

Ti alaboyun ba si n rọbi, inu irora ni wọn yoo ti gbe jade lọ si ilu miran lati lọ bimọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n ba BBC sọrọ, Hanna Kosinah to diwọ-disẹ sinu salaye pe, oju oun ri mabo, ki oun to ri ọkọ ti yoo gbe oun lọ si ilu miran, lasiko ti oun n rọbi lati bi akọbi oun.

Agba ilu kan, to fi idi eewọ naa mulẹ ni, ohun kan lo fọ lati ọrun si awọn baba nla awọn pe awọn ko gbọdọ bi ọmọ, sin oku tabi ẹran sinu ilu naa, tori ilu mimọ ni.