Mansa Musa: Ó lówó, ó ní dúkìá rẹpẹtẹ àmọ́ kò pẹ́ láyé

Mansa Musa Image copyright @ItsMansaMusa

Oludasilẹ ile iṣẹ Amazon, Jeff Bezos lo lowo julọ lagbaye bayii gẹgẹ bi atẹjade ti iwe iroyin Forbes gbe fi lede, pẹlu owo to le ni biliọnu lọna aadoje owo dọla ($131bn)

Ṣugbọn iwadii fihan pe, ọmọ ilẹ Afririka lo lowo julọ lagbaye ninu itan ni Mansa Musa.

Musa jẹ aarẹ apaṣẹ waa ni ẹkun Gusu ilẹ Afirika laye ọjọ-un ti o fi orilẹede Mali ṣe ibujoko ijọba rẹ.

Iwadii fihan pe owo ti Musa ni nigba naa, to bi biliọnu lọna irinwo dọla ($400bn) owo ode oni.

Ọjọgbọn ninu imọ itan ni fasiti California lorilẹede Amẹrika, Rudolph Butch Ware sọ pe, ko rọrun lati sọ iye owo ti Musa ni ni pato, nibi ti o lowo to si lọrọ de laye igba yẹn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Musa: Igi owo

Onwoye Jacob Davidson kọ nipa Musa lọdun 2015 pe, Musa lọrọ ju ohun tẹni kankan le ṣalaye lọ.

Ibi Musa

Wọn bi Mansa Musa lọdun 1280 si idile awọn to ṣe olori. Ẹgbọn Mansa, Abu-Bakr se ijọba titi di ọdun 1312.

Ọdun 1312 yii lo fipo naa silẹ, to si gbera lọ si oke okun pẹlu ẹgbẹrun meji ọkọ oju omi ati ẹgbẹẹgbẹrun ọkunrin ati obinrin ti wọn ko si pada wale mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDemilade Adepegba: Mo má a ń gbàgbé fèrè ni, tí mo bá wà nílé ìwé

Bayii ni Musa bẹrẹ si ni ṣe ijọba lẹyin ti ẹgbọn rẹ lọ ajo aremabọ.

Ijọba Musa lọ ṣua bi ẹgbẹrun meji mailli lati eti okun to fi de ibi ti orilẹede Niger wa loni.

Koda ijọba rẹ tun tan ka de awọn apa kan lorilẹede Senegal, Mauritania, Burkina Faso, Gambia, Guinea Bissau, Guinea ati orilẹede Ivory Coast.

Maapu Ijọba Mansa Musa

Bi ijọba rẹ ṣe tan kalẹ to, bẹẹ naa ti alumọni goolu ati iyọ pọ yanturu ni ijọba rẹ.

Ibudo iko nnkan iṣẹnbaye lọjọ si ti ilẹ Gẹẹsi sọ pe, idaji goolu to wa lagbaye lo wa ni ijọba Musa nikan laye igba yẹn.

Ibudo okoowo goolu wa kaakiri ni ijọba rẹ, nidi okoowo yii lo ti ri owo to towo.

Irinajo Musa si Mecca

Okiki ijọba Musa kan kari aye nigba to lọ si ilu Mecca fun iṣẹ isin, to si gba ọna aṣalẹ Sahara ati orilẹede Egypt lọ irinajo ọhun.

Iwadii fihan pe, ẹgbẹrun lọna ọgọta ọkunrin lo kọwọ rin pẹlu Musa lọ si ilu Mecca.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Musa olowo aye

Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ aafin rẹ, awọn sọja, awọn oniṣowo, awọn ti n wa kẹtẹkẹtẹ pẹlu ẹru kọwọ rin pẹlu Musa lọ si ilẹ mimọ.

Musa tun ko ọpọlọpọ ewurẹ ati agutan dani, ti wọn n pa fun ounjẹ loju ọna.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Musa jẹ musulumi gidi

Musa sọ ilu Tumbuktu lorilẹede Mali di gbajugbaja lagbaye, lẹyin ti okiki aworan ijoko ọba ti wọn fi goolu ṣe lori maapu Catalan lọdun 1375, se gba awujọ agbaye kan.

Musa ku lọdun 1337 ni ẹni ọdun mẹtadinlọgọta, lẹyin naa lawọn ọmọkunrin rẹ bẹrẹ si ni ja si ẹni ti yoo gun ori itẹ baba wọn.

Eleyi lo jẹ ki ijọba naa tu, ki awọn oyinbo to wa ko ilẹ Afirika lẹru.