Demilade Adepegba: Mo má a ń gbàgbé fèrè ni, tí mo bá wà nílé ìwé

Demilade Adepegba: Mo má a ń gbàgbé fèrè ni, tí mo bá wà nílé ìwé

Ohun iyalẹnu lo jẹ fun BBC Yoruba lati ri ọmọdekunrin kan, ọmọ ọdun mẹwa, Demilade Adepegba to n fọn fere ni ode ariya bii agbalagba.

Ọmọ ọdun mẹwa naa ni oun nifẹ fere fifọn pupọ, awọn ẹgbẹ akọrin kan to maa n fọn fere si lo se iwuri fun oun lati yan fere fifọn ni aayo.

Demilade ni ẹru kii ba oun ti mama oun ba wa lode ariya, ti oun si n fọn fere, nitori oun kii wo oju rẹ, oun yoo gbe oju soke ni, ki ẹru ma baa maa ba oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe fere fifọn ko di iwe oun lọwọ nitori pe, oun kii ranti fere fifọn rara lasiko ti oun ba n kẹkọ lọwọ.

Demilade wa rawọ ẹbẹ si awọn obi lati maa ti ọmọ wọn lẹ́yìn nínú ohun gbogbo tí wọ́n bá fẹ́ ṣe, kò báà jẹ́ eré bọ́ọ́lù, àwòrán yíyà àbí gìtá títa.