Ìtàn Mánigbàgbé: Baṣọ̀run Gáà jẹ́ àgbà ìjòyè tó le è yípadà sí ẹranko tó bá wù ú

Basorun Gaa Image copyright Steemit

Ko fẹẹ si ọmọ Kaarọ o jiire ti ko gbọ orukọ Basọrun Gaa ri nitori odu ni, kii se aimọ fun oloko.

Koda, owe kan wa, to jẹ mọ iwa ati ise Basọrun Gaa, eyi to ni ‘Bo laya ko sika, to ba ri iku Gaa, ko sootọ’, eyi to se alaye nipa awọn iwa ika ti Basọrun Gaa hu lasiko to gbe ile aye.

Gẹgẹ baa ti ka ni oniruuru awọn oju opo ikansiraẹni lori itakun agbaye, kii kuku se pe Basọrun Gaa ko ni ipa rere to ko si idagbasoke ilu rẹ, Ọyọ ile, nitori ti ko ba jẹ eeyan takuntakun, ko ni de ibi giga to ku si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Itan fi ye wa pe, Basọrun Gaa ni olori igbimọ Ọyọmesi, eyi to dabi Olootu ijọba laye ode oni, lẹyin Alaafin, tii se oriade ilu Ọyọ́, Basọrun Gaa lo tun ku.

Ko si sẹni to lee sọ pe ti Basọrun Gaa ko jẹ eeyan gidi, wọn yoo fi jẹ oye Basọrun, to jẹ olori igbimọ lọbalọba fun Alaafin, tii se Ọyọmesi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDemilade Adepegba: Mo má a ń gbàgbé fèrè ni, tí mo bá wà nílé ìwé

Ni bayii, o wa yẹ ka mọ itan igbe aye akọni yii ati ipa to ko ni ilu rẹ, boya rere ni abi buburu.

Itan igbe aye Basọrun Gaa:

 • Basọrun Gaa ni olori ogun Ọyọ ile ati gbajumọ ilu ni saa onka ẹgbẹrun ọdun kẹtadinlogun si ikejidnlogun, 17th/18th century
 • Basọrun Gaa se gudugudu meje ati yaa ya mẹfa lati ri daju pe Ọyọ ile akọkọ di ilu nla, o lagbara, to si fẹ de ọpọ ilu ati orilẹede lode oni
 • Lọdun 1750 ni Alaafin Labisi yan Gaa gẹgẹ bii Basọrun, olootu ijọba ati olori igbimọ lọbalọba ẹlẹni meje fun Alaafin nilu Ọyọ ile, ti agbara si n pa Gaa bi ọti
 • Ilu Ọyọ ile roju, o tuba, o tusẹ lasiko ti Basọrun Gaa joye, ti Ọyọ si maa n gba isakọlẹ lati ọpọ ilu àmọ́nà to wa labẹ rẹ
 • Tọmọde-tagba nilu Ọyọ lo n bẹru, ti wọn si n bọwọ fun Basọrun Gaa, tori pe o ni oogun abẹnu gọngọ, ti asẹ rẹ si mulẹ ni aarin ilu ju Alaafin Labisi to yan sipo lọ
 • Itan sọ pe Basọrun Gaa ni oogun pupọ, to si maa n parada di ẹranko to ba wu, to fi mọ Ẹkun, Kiniun, Igala, Ọya ati bẹẹ bẹẹ lọ
 • Ni kete ti Gaa di Basọrun ni Ọyọ ile lo pa meji ninu awọn ọrẹ imulẹ Alaafin Labisi, eyi to dun ọba naa de egungun, to si gba ẹmi ara rẹ lọdun 1750 naa
 • Alaafin Awọnbioju lo jẹ Alaafin lẹyin Labisi, sugbọn niwọn igba toun naa kọ lati gba itọni lọdọ Basọrun Gaa, aadoje ọjọ pere lo lo lori itẹ ti Gaa fi ni ki wọn yẹju rẹ
 • Alaafin Agboluaje to jẹ lẹyin Awọnbioju tiẹ ri ijọba se ntiẹ, tori o n gbọrọ si Basọrun Gaa lẹnu, sugbọn ọwọ Basọrun Gaa naa ni ẹmi rẹ papa bọ si
 • Alaafin Majẹogbe tiẹ lo dun kansoso pere lori itẹ, ki Basọrun Gaa to ran sọrun ọsan gangan
 • Lọdun 1774 ni Alaafin Abiọdun gori itẹ, to si n wọna bi yoo se rẹyin Basọrun Gaa, ko lee roju se aye, sugbọn Gaa pa ọmọbinrin Alaafin Abiọdun, Agbọrin, nigba to nilo ẹranko Agbọnrin, to si ni orukọ wọn jọra
 • Ọrọ naa dun Abiọdun to bẹẹ, to si beere fun atilẹyin Onikoyi, ati aarẹ Ọna Kakanfo to jẹ nigba naa, Ọyalabi lati ilu Ajasẹ ipo, ki wọn lee tete rẹyin Basọrun Gaa
 • Alaafin Abọdun kọkọ yọ ibẹru Gaa kuro lọkan awọn araalu, to si jẹ ki ibinu rẹ maa ru jade ni inu wọn, titi ti Basọrun Gaa fi rọ lapa, rọ lẹsẹ
 • Lọdun 1774, ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan Ọyọ ile ya bo agboole Basọrun Gaa, ti wọn si wọ lọ si ọja Akẹsan, ki wọn to sun nina gburugburu, bẹẹ ni wọn pa tọmọtọmọ, wọn jẹ ile Gaa run patapata
 • Sugbọn ori ko akọbi rẹ, Ojo Aburumaku yọ ninu wahala yii, to si sa lọ si ilẹ Ibariba, eyi to fopin si aye fami lete kintutọ ti Basọrun Gaa ati idile rẹ n jẹ
 • Idi ree ti awọn eeyan se maa n pa asamọ pe ‘Bo laya ko sika, to ba ri iku Gaa, ko sootọ’
 • Sugbọn iku Basọrun Gaa se akoba nla fun ijọba Ọyọ akọkọ, tori lẹyin iku Gaa ni adinku ba bi awọn ọmọ ogun rẹ ti dangajia si ati agbara ilu naa, tawọn ilu kan si n sa kuro labẹ rẹ, titi ti Ọyọ ile akọkọ fi tu lọdun 1836.

itan igbe aye Basọrun Gaa yii ni ọpọ ẹkọ to kọ wa, paapa awọn alagbara lode aye, o si kọ wọn pe ki wọn rọra se.

Image copyright Getty Images

Bakan naa ni itan igbe aye Basọrun Gaa yii kọ wa lati mase se ika nitori ati oore, ati ika, ọkan kii gbe, ati ile aye yii si la ti jere gbogbo iwa ta ba hu, ta si gba ẹsan rẹ lrun pẹlu.

Gbogbo awa obi si lo yẹ ka ranti pe agba to ba ro ẹfọ ika, ọmọ rẹ yoo jẹ ninu rẹ, bẹẹ si lo yẹ ka wa ọna lati fi orukọ rere silẹ de iran wa to n bọ nitori orukọ rere san ju wura ati fadaka lọ.